Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Onísáàmù náà nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, ó sì pa á mọ́ -- èyí tí ó fún un ní ọgbọ́n, ìmọ̀, òye àti ìmọ́lẹ̀. Ó pámọ́ kúrò ní ọ̀nà tí kò tọ́ àti kúrò lọdọ oníṣẹ́ ibi.
Kí ló túmọ̀ sí?
Àyọkà wá ti òní ṣe àpèjúwe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní tó wà nínú pé ká nífẹ̀ẹ́ àti ká ṣè ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ká mọ ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí orísun alakọkọ fún ìgbé ayé rẹ fún Òní sáàmù náà ni ànfàní lórí àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn olùkọ́ rẹ̀ àti àwọn alàgbà rẹ̀ pẹ̀lú. Bi ìmọ̀ wọ́n ti pọ̀ tó kó tó ìjìnlẹ̀ òye; bẹ́ẹ̀ náà ni ọjọ́ orí wọn tàbí ìwòye ayé wọn kò tó ọgbọ́n tàbí agbára láti lóye bí Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ayé. Ọlọ́run kò ṣe àfihàn gbogbo ohun tí òǹkọ̀wé náà nílò láti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa kíkọ́ ẹ̀kọ̀ òfin àti pípa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ fún un ní ìmọ́lẹ̀ tó pọ̀ tó fún ní ipa ọ̀nà tó wà níwájú rẹ̀. Ó jẹ́ kó mọ ìyàtọ̀ láàrín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ó sì mú ìbẹ̀rù tó jinlẹ̀ jù lọ kúrò lọ́kàn rẹ̀. Ó ní àfojúsùn pé òun á máa bá Olúwa rìn títí dé òpin ìgbésí ayé òun, ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú ìmọ́lẹ̀
Báwo ní kí ń ṣe dáhùn?
Àwọn orísun wo lo gbẹ́kẹ̀ lé? Ṣé o ní lọ́kàn pé ẹ̀kọ́ tí o kà ní ó rò wípé yíò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lè lò ígbésí ayé rẹ bí ó ti tọ́ àti bí ó tí yẹ́? Bóyá o máa ń gbára lé ìmọ̀ràn òbí rẹ tàbí ti ẹ̀gbọ́n láti tọ́ ọ sọ́nà nínú àwọn àṣàyàn rẹ. Ẹ̀kọ́ ìwé àti ìrírí ṣíṣe ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n wọn kò mú ìdánilójú òye àti ìmọ̀ ò lè mú kó o ní òye tàbí ìmọ́ tó lè jẹ́ kí ó ṣe ìpinnu tó mú ọ́gbọ́n dání. Bíbélì nìkan ṣoṣo ni orísun tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tó sì jẹ orísun aláìlẹ́gbẹ́ fún ìyè. Bí o ṣe ń ṣè ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní ẹ̀ka kan, Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ si tan ìmọ́lẹ̀ sí èrò inú rẹ pẹ̀lú òye àti ìmọ̀ púpọ̀ sí i láti darí rẹ (Jòhánù 7:17).Irú ipò tàbí ìbásepọ̀ wo lo nílò ọgbọ́n Ọlọ́run fún? Wá inú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lónìí -- Òun yóò fún ọ ní òye láti mọ rere kúrò nínú búburú àti láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó dára àti ohun tí ó dára jù.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More