Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Onísáàmù náà wà nínú ìpọ́njú, ó sì ń retí ìtùnú l'áti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó mọ̀ wí pé Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́ àti aláàánú; ó gbé ìrètí rẹ̀, ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀, àti ìgbọràn rẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọ́run.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Onísáàmù náà ti fi Ọlọ́run s'ílẹ̀ ní ọ́nà kan tàbí òmíràn, àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ń ṣe inúnibíni sí i gan-an. Ìṣòro rẹ̀ mú u sún mọ́ Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní ibi tí a ti rán-an l'étí ìdúróṣinṣin àti àánú Olúwa. Òǹkọ̀wé náà wá rí i pé oore àti ìṣòtítọ́ Ọlọ́run ní fi ààyè gba ìjìyà rẹ̀. Ìbá tẹ̀ s'íwájú l'áti máa ṣe àìgbọràn sí Ọlọ́run, tí ìwà rẹ̀ kò sì ní yí padà. D'ípò tí ì bá fi máa ro'nú ní'pa ipò tí ó bá ara rẹ̀ ní ákókò yẹn, ó gbé ojú lé ìṣeéfọkàntán ayérayé Ìwé Mímọ́ l'áti da'rí àwọn ìgbàgbọ́ àti ìdáhùn rẹ̀. A lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Kí ni ó yẹ kí n ṣe?
A sábà máa ń sọ pé ìdúróṣinṣin Ọlọ́run túmọ̀ sí wí pé yíÒ dá wa n'ídè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kúrò l'ọ́wọ́ ohunkóhun tí ó bá ń kó ìdààmú bá wa. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run lè jẹ́ kí ìpọ́njú dé bá ẹ kí o lè yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ padà, kí ó mọ irú ẹni tí o jẹ́, tàbí kí ó mú kí o padà gbára lé E. Ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú ìjìyà èyíkéyìí ni wí pé ó máa ń jẹ́ kí o lè rí ohun tí ó wà ní ita. Ohun gbogbo tí ó bá sún ọ dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní èrè - bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé ó ń dun'ni. Ibo ni o ti ń wá ìrètí àti ìtùnú báyìí? Ṣé ìwo á jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ máa da'rí ìrònú àti ìmọ̀lára rẹ? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, láì ka ipò yòówù tí o wà l'ónìí sí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More