Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 88 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Onísáàmù náà bẹ Olúwa pé kí ó fún òun ní òye kí ó sì yí ọkàn òun padà sí àwọn òfin Ọlọ́run. Ó ṣe ìgbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run, ó sì rí ìtùnú nínú àwọn ìlérí àti òfin Rẹ̀.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Ẹni tí ó kọ Sáàmù 119 pàtàkì kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìfẹ́ tí ó ní l'áti mọ ohun tí ó wà nínú Bíbélì kọjá níní òye nípa Ọlọ́run nìkan; ohun tí ó fẹ́ ni wí pé kí ó ní òye ohun tí Ìwé Mímọ́ túmọ̀ sí kí ó bàa lè máa fi ohun tí ó wà nínú rẹ̀ sí ìlò ní gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ̀. Bí ó ti ń b'ọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run, ó yí padà kúrò nínú lílépa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti ara rẹ̀, ó sì fẹ́ l'áti gbé ìgbésí ayé rẹ̀ fún àwọn nǹkan tí ó n'íye l'órí títí láé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ṣíṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run kò mú kí àwọn ìṣòro rẹ̀ d'ópin, ìtùnú tí o rí nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run fún-un ní ìrètí tí ó wà pẹ́ títí.

Bàwo ni kí n ṣe dáhùn?

Kí ni ó sún ọ l'áti ka ìwé ìfọkànsìn yìí? Ṣé o fẹ́ yan'jú ìṣòro kan, kí o rí ìtùnú, tàbí kí o tú bọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn dára, ẹsẹ̀ Bíbélì tí a kà l'ónìí ń fún wa ní ìṣírí wí pé kí a máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a sì máa fi í s'ílò. Ìyípadà á bẹ̀rẹ̀ síí wáyé nínú ìgbésí ayé rẹ bí o ṣe ń ní óye Ìwé Mímọ́, tí ò ń kọ'bi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀, tí o sì ń ṣè ìgbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Ìyọrísí rẹ̀ á wá dà bíi ìgbà tí wọ́n ń ju kẹ̀kẹ́ domino sí'wá s'ẹ́yìn - ìwọ á túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ìwọ á mọ bí o ṣe lè yan'jú onírúurú ìṣòro, ìwọ á rí ìtùnú àti ìrètí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bẹ Ọlọ́run wí pé kí Ó fún ọ ní òye àti ìrètí ayérayé bí o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí o sì ń k'ẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kí o sì máa fi òtítọ́ tí ó ṣí payá s'ílò. Bíbélì kíkà kìí wulẹ̀ ṣe àṣà tí ó dára nìkan, ó ń yí ènìyàn padà.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org