Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kini ó sọ?
Òǹkọ̀wé náà yín Ọlọ́run fún dídá tí ó dà ayé nípa ọgbọ́n; ó sì ṣe ìlérí láti máà kọrin ìyìn sì Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí òun bá wà láàyè
Kini ó túmọ̀ sí?
Orin Dáfídì 104 jẹ́ orin ìyìn míràn sì Ọlọ́run fún ìṣẹ̀dá Rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu àti àṣẹ Rẹ̀ lórí gbogbo ilé ayé. Olúwa Ọlọ́run nìkan ni Ó lágbára tó sì ni ọgbọ́n láti ṣètò àgbáyé ni ìlànà pípé. Ọlọ́run tó dá àgbáyé tí yàn láti ṣe àfihàn ohun Ìkọ̀kọ̀ Rẹ̀ sì ìṣẹ̀dá Rẹ̀ pàtàkì - ènìyàn - ẹni tí Ó fẹ́ láti bá ní àjọṣepọ̀ ni ẹnisíẹni. Ó pèsè ohun gbogbo tí àwọn ènìyàn nílò láti gbé ní ìrọ̀rùn láàrin ìṣẹ̀dá Rẹ̀ - omi, oúnjẹ, àti ohun èlò fún aṣọ àti ibi gbígbé pẹ̀lú. Ìdáhùn ọmọ-ènìyàn kò gbọ́dọ̀ kéré ní ìwọ̀n sì ìjọsìn fún Ẹlẹ́dá àti Aláṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Ìrísí ẹwà ìṣẹ̀dá olọ́kanòjọ̀kan lè fà ìwárìrì ojú-ẹsẹ̀ - ni wíwo òṣùmàrè, wíwọ̀ óòrùn, tàbí ìdà-omi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ. Kòsí àsìkò to dára jù fún wa láti fi ìyìn fún Olúwa ju àwọn àkókò wọ̀nyí lọ. Ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run àti ìjọ̀wọ́ ara ẹni sì àṣẹ Rẹ̀ fojú hàn gbangba nínú ìgbé ayé ẹni tí ó gbàgbọ́ ni òdodo pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dágbogboohun àti Aláṣẹlóríohun gbogbo. Ǹjẹ́ ó bù ọlá fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dá Rẹ̀ bí? Báwo ni ìgbé ayé rẹ ṣe sàfihàn pé Òun ni Olúwa àti Ọba rẹ? Ìgbé ayé rẹ yíò jẹ́ ti ìjọsìn bí ó bá lè bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nípa ìdánimọ̀ ẹni tí Ọlọ́run íṣe.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More