Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Àwọn ènìyàn Ísráẹ̀lì gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sin ère òrìṣà, Wọ́n kẹ́gàn Ilẹ́-Ìlérí, wọ́n kùn nínú àgọ́ wọn, wọ́n sì fi àwọn ọmọ wọn rúbọ, ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olótìtótọ́ síbẹ̀.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Àìsòótọ́ Ísráẹ́lì tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ ní Sáàmù 106 yàtọ̀ gédégédé sí àfiwé bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ olóòótọ́ nínú Sáàmù 105. Wọ́n gbàgbé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run rántí! Oníwàásù ìlú Scotland kan, George Morrison kọ ìwé pé, “Olúwa mú Ísráẹ́lì jáde ní ilẹ̀ Íjíbítì ní alẹ́ kan, ṣùgbọ́n ó gbà Á ní ogójì ọdún láti mú Íjíbítì kúrò nínú ìwà àti ìṣe Ísráẹ́lì.” Àwọn ènìyàn Ọlọ́run bọ́ sí inú ìdẹkùn àṣà àwọn tí kò mọ Ọlọ́run dípò kí wọ́n gbé ìgbé-ayé oníwà-bí-ọlọ́run tí ó bu ọlá fún Olúwa wọn tí ó jẹ mímọ́. Fíníásì nìkan ní ìtànsán ìmọ́lẹ̀ láàrin àkọsílẹ̀ àkókò òkùnkùn yìí – ó gba Ọlọ́run gbọ́, ó dá sí, a sì kà á sí bí olóòótọ́. Bíótilẹ̀jẹ́pé Ísráẹ́lì kò gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, wọ́n kò sì gbọ́ràn sí pẹ̀lú, Óun jẹ́ olóòótọ́ síbẹ̀ sí májẹ̀mú ayérayé Rẹ̀, Ó sì gbà wọ́n nígbàtí wọ́n kígbe pe E
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Àwọn ìṣe àti ìhùwàsí wo nínú Sáàmù yìí ni ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú ayé rẹ – ìlara, ìkùnsínú, àìgbọràn, ìṣelòdì? A lè kọ́ ẹ̀kọ́ nínú àṣìṣe àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kí àwa náà má baá bọ́ sí inú ìdẹkùn àṣà àwọn aláìwàbíọlọ́run ní àyíká wa. Pọ́ọ̀lù Àpóstélì ṣe àtòjọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀ bíi ìkìlọ̀ láti má bọ́ sí inú irú ẹ̀ṣẹ̀ kan náà (1 Kór. 10:1-13). Báwo ni Ọlọ́run ṣe dára sí ọ ní ọ̀sẹ̀ yìí, ní àìkà èrò tàbí ìwà rẹ tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ sì? Òtítọ́ Rẹ̀ gbọdọ̀ ru ẹ̀mí ìmoore àti jíjọ̀wọ́-ara-ẹni ní ìrẹ̀lẹ̀ fún ìfẹ́ Rẹ̀ sí òkè nínú rẹ. Báwo ni ìgbé ayé rẹ ṣe lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn ẹlòmíràn láti lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé kí wọ́n sì ṣe ìgbọ́ràn sí Ọlọ́run?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More