Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
N'ígbà tí ó ń yin Ọlọ́run fún ìfẹ́ àti ìṣòtítọ́ Rẹ̀, Dáfídì bẹ̀ Ẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ ó sì pe Ọlọ́run l'áti gb'ẹ̀san l'ára àwọn ọ̀tá rẹ̀
Kí ni itúmọ̀ rẹ́?
Dáfídì ṣí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sáàmù wọ̀nyí pẹ̀lú ìyìn tí ó rán-an l'étí ẹni tí ó ń gb'àdúrà sí. Ó tú ọkàn rẹ̀ sí Ọlọ́run pẹ̀lú ìbínú l'órí àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí ń kọlù-ú láìsí ìdí àti àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run yàn. Ó jẹ́ kàyéfì fún Dáfídì ìdí tí ó dà bíi wí pé Ọlọ́run dá èsì Rẹ̀ dúró sí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n rò wí pé àwọn èniyàn mímọ́ Májẹ̀mú Láíláí kò mọ̀ nípa ọjọ́ ìdájọ́ kan, ní'torí náà wọ́n bèèrè l'ọwọ Ọlọ́run l'áti ṣe déédé ìdájọ́ Rẹ̀ ní kíkún lẹ́sẹ̀kesẹ̀. Ní ìparí, Dáfídì kò wá ẹ̀san fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ó dúró de Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́, ní'torí ó mọ̀ wí pé agbára ènìyàn nìkan kò ní tó.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Ṣé o ń kojú àtakò láì sí ẹ̀bi kankan ní ọ̀dọ̀ rẹ? Àwọn ipò rẹ kò ju agbára Ọlọ́run lọ. Kìí ṣe ìwọ nìkan lo wà nínú ìjà náà. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé ipò náà kò yí padà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tàbí tí ó bá jọ wí pé Ọlọ́run dákẹ́, rántí wí pé Ó rí i, Ó mọ̀, Ó sì bìkítà. Gb'àdúrà, sọ fún-Un ní pàtó bí ó ṣe rí nínú ọkàn rẹ, kí o sì dúró dè È l'ati jà fún ẹ. Ṣé ìwọ á gbé ara lé agbára rẹ l'ónìí tàbí agbára Ọlọ́run l'áti mú ọ kọ já? Dípò kí ó gbá'jú mọ́ ìṣòro náà, gbẹ́kẹ̀ lé E kí o sì gb'óríyìn fún Ẹni tí ó ní ọ̀nà àbáyọ - Olúwa Jésù Kristi.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More