Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 80 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Ọlọ́run dára! Àánú rẹ̀ dúró títí láé. Kí àwọn tí Olúwa ti rà padà máa dúpẹ́ fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì. ì yẹ àti àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

Kí ló túmọ̀ sí?

Òǹkọ̀wé náà sọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ àrà tí ó lókìkí tí Olúwa ṣe fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ tí ó rà padà. Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ nínú ipò lílekoko kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ ó dà bíi pé wọn kò dáwọ́ dúró láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀, láti yìn ín, tàbí láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. A ní láti rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé kí wọ́n fi ẹ̀mí ìmoore hàn bí Ọlọ́run ṣe dá sí ìrírí ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé wọn. Ó ṣiṣẹ́ nínú ipòkípo tí àwọn ọmọ Rẹ̀ wa láti mú ìlànà Rẹ̀ ṣẹ fún ìgbésí ayé wọn. Bí a ti ṣe mọ ìlọ́wọ́sí ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn ìmoore jẹ àpẹẹrẹ wípé wọn jẹ́ ọlọgbọ́n.

Kí ló yẹ kí n ṣe?

Ọlọ́run bìkítà nípa ọ̀rínkiniwí ìgbé ayé rẹ. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ìgbésí ayé kò ní ìṣòro, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lè lo ipò èyíkéyìí - láìka bí ó ṣe le tó - láti ṣe àṣeyọrí nínú àwọn ìdí tí wọn fí wá sí ayé nípa ìlànà rẹ̀ nínú àti nípasẹ̀ ayé rẹ. Nipasẹ ipọnju, Oluwa lè mú igbagbọ rẹ dàgbà sókè, ní igbẹkẹle lori Rẹ, ati ọkàn ìmoore fun ìlọ́wọ́sí Rẹ nínú ayé wa. Irú ipò wo ló wà tí Ọlọ́run fi dá sí ọ̀rọ̀ ayé rẹ? Kíni Ọlọ́run pèsè fún ọ ní ọ̀sẹ̀ yìí? Ló akoko díẹ̀ loni lati dupẹ lọwọ Rẹ ati lati sọ fun ẹlòmíràn ohun ti ìfẹ́ nla rẹ túmọ̀ si fun ọ.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org