Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Dáfídì yin Ọlọ́run nítorí pé ó mú àwọn ìrékọjá rẹ̀ kúrò gẹ́gẹ́ bí ìlà-oòrùn ti jìnnà réré sí ìwọ̀-oòrùn.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Sáàmù yìí jẹ́ orin ìyìn tí Dáfídì kọ, ó sì jẹ́ ká mọ ìdí tí a fi pe Dáfídì ní "ẹnì bíi ọkàn Ọlọ́run." Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé eléyìí ni ewì ìyìn tótayọ tó sì lọ́lá jù lọ tí wọ́n tíì kọ sí Ọlọ́run. Láìsí pé Dáfídì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Olúwa, ó rọ àwọn olùjọsìn tó ń kọ orin yìí pé kí wọ́n máa rántí àwọn àǹfààní tó wà nínú sísin Ọlọ́run: ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, ìmúniláradá, ìràpadà àti ìtẹ́lọ́rùn. Ìtara tí Dáfídì ní fún Olúwa rẹ̀ wá pọ̀ sí i nígbà tó wá mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tí Ó ti ṣe.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Ìgbà wo lo gbàdúrà kẹ́yìn láì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Ọlọ́run? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè bẹ̀rẹ̀ àdúrà wa pẹ̀lú ọpẹ́ sí Olúwa fún oore rẹ̀ sí wa, síbẹ̀ a sábà máa ń yára lọ sórí ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ ní àkókò yẹn. Ṣe àkọsílẹ̀ ìyìn àti ìdúpẹ́ lọ́sẹ̀ yìí, nígbà tó o bá sì ń gbàdúrà, lo àwọn èrò wọ̀nyẹn láti yí ọkàn àti èrò inú rẹ padà sí ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tí Ó ti ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ. Béèrè fún àwọn nǹkan pàtó, kí o sì dúpẹ́ fún àwọn ìdáhùn pàtó sí àdúrà. O tiẹ̀ lè gbìyànjú láti gbàdúrà fún ìṣẹ́jú mẹ́ta sí márùn-ún láì béèrè ohunkóhun rárá. O lè bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó wà nínú Sáàmù 103 kí o sì gbàdúrà sí Olúwa nípa wọn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More