Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni o sọ?
Àwọn ọ̀tá Olúwa yíò di àpótí ìtìsẹ̀ Rẹ̀, àti pé yíò ṣe àkóso wọn gẹ́gẹ́ bíi àlùfáà nípa àṣẹ Mẹ́lkisẹ́dèki
Kíni ó túnmọ̀ sí?
Orin Dáfídì 110 sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Kristi bíi Àlùfáà ayérayé. A ṣe àfihàn Kristi gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run, Ọba, Àlùfáà, Adájọ́, àti alágbára Jagunjagun. Orin alásọtẹ́lẹ yìí ṣe àkàwé ìtakùrọ̀sọ láàárín Ọlọ́run Baba àti Ọlọ́run Ọmọ. Dáfídì ní ìwúrí l'áti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọ nípa Ọba kan tí ó ń bọ̀ tí kò ní jẹ́ ọmọ nìkan ṣùgbọ́n Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú. A ṣe àtúnwí Sáàmù yìí nínú májẹ̀mú túntún jú èyíkéyìí àwọn Sáàmù tí ó kù lọ. Jésù ṣe àtúnwí rẹ̀ ní ìgbà tí Ó béèrè l'ọ́wọ́ àwọn olóríi Júù wí pé báwo ní Kristi ṣe lè jẹ́ ọmọ Dáfídì kí Ó sì tún jẹ́ Olúwa rẹ̀ (Mátíù 22). Àwọn olùkọ́ òfin kò ní ìdáhùn síi ní'torí pé kò yé wọn wí pé Mèsáyà (Kristi) gbọ́dọ̀ jẹ́ ènìyàn àti Ọlọ́run ní ìgbà kan náà.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Apá kan àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà ní Orin Dáfídì 110 ti wá sí ìmúṣẹ nípa ikú, ìsìnkú, àjíǹde, àti ìgòkè Ọmọ Ènìyàn àti Ọmọ Ọlọ́run, Olúwa Jésù Kristi. Apá kejì àsọtẹ́lẹ̀ náà - nípa ìdájọ́ àwọn tí ó kọ Kristi àti èrè àwọn tí ó ṣe tí Kristi - yíò wá sí ìmúṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe ìlérí. Ó ń ṣiṣẹ́ l'ọ́wọ́ ní ìgbésí ayé àwọn tí ó ń tọ̀ Ọ́ l'ẹ́yìn gẹ́gẹ́ bíi Ọba àti Olórí Àlùfáà. Ǹjẹ́ o ṣe bẹ́ẹ̀ mọ̀ Ọ́? Iṣẹ́ tí a rán sí wa l'ónìí yé wa dájú - Ọlọ́run yíò wá pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bíi Adájọ́, èto Rẹ̀ yíò sì wá sí ìmúṣẹ. Ìyàtọ̀ wo ni òtítọ́ yẹn mú jáde ní ìgbésí ayé rẹ? Báwo ní ó ṣe máa lo àkókò rẹ ní ayé kí ó baà lè wúlò ní ayérayé?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More