Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Onísáàmù náà gbé oríyìn fún Ọlọ́run fún ìṣòtítọ́ Rẹ̀ sí májẹ̀mú ayérayé tí Ó bá Ábráhámù àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ dá.
Kí ni itúmọ̀ rẹ́?
Sáàmù yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ìtàn Israẹli, ó sì fi ìṣàkóso àti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run hàn nínú ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú Israẹli. Onísáàmù náà gba Israẹli ní ìyànjú láti rántí ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn àti láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn. Orílẹ̀-èdè Israẹli ti ní ìrírí ààbò, ìpèsè, àti ìlérí Olúwa fún'ra rẹ̀. Ní ìgbà ìjọba Dafidi ọba, àwọn ọmọ Léfì ka apá kan Sáàmù 105 ní ìgbà tí Àpótí Májẹ̀mú padà wá (1 Kíró. 16). Ìrántí òtítọ́ Ọlọ́run àtijọ́ máa ń mú ìmoore àti ìgbọràn lọ́wọ́lọ́wọ́ wá.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Rántí ìgbà tí... Ìbéèrè yẹn fẹ́rẹ̀ẹ́ máa ń fa ìrántí ayọ̀ àti ẹ̀rín bí o ṣe ń ronú padà lé àwọn àkókò pàtàkì. Àkọsílẹ̀ òtítọ́ Ọlọ́run nínú àyọkà òní rán wa l'étí ìfẹ́ àti títóbi Rẹ̀. Ìgbà mélòó ni o máa ń sọ nípa àwọn ohun tí o rántí nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ olóòótọ́ nínú ayé rẹ? Ọlọ́run máa n rántí ní ìgbà gbogbo ó sì ń mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Báwo ni o ṣe sábà máa ń rántí l'áti gbẹ́kẹ̀ lé É kí o sì dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Rẹ̀? Ìdúróṣinṣin Ọlọ́run ní ìgbà àtijọ́ jẹ́ ìdí tí ó fi yẹ kí a máa dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Rẹ̀ nísinsìnyí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More