Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ohun tí ó so?
Onísáàmù ń kígbe nínú ìpọ́njú, ó ń bẹ Olúwa láti gbọ́ àdúrà rẹ̀ àti igbe rè fún ìrànlọ́wọ́.
Kí ni o túmọ̀ sí?
Ẹni tí ó kọ Sáàmù 102 ní ẹ̀dun ọkàn tí ó pọ̀ dé ibi pé; ó ronú pé Ọlọ́run ti pa òun tì. Ṣùgbọ́n nínú ìdààmú rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Ọlọ́run:. Ìwà Rẹ̀, ipò ọba aláṣẹ Rẹ̀, àti ìrètí pé Ọlọ́run yóò dá a nídè kúrò nínú wàhálà rè. Lẹ́yìn náà ni ó wá rántí pé àwọn míràn ń wo ohun tí ó ń ṣe ní ìdáhùn. Ó wo àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwọn tí ó máa mọ̀ pé Ọlọ́run ti jẹ́ olóòótọ́ láyé àtijọ́ àti lóde òní, àti pé yóò máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ síí yin Ọlọ́run, ó sì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn pé rere ni Ọlọ́run!
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Njẹ́ ìwọ – bíi ẹni tí ó kọ Sáàmù 102 – ri ara rẹ ní wákàtí tí ó ṣe òkùnkùn jù lọ, tí ò ń ronú nípa àwọn àdánwò tí ó ń tán ọ lókun? Ohun tí kò wù ẹ́ láti ṣe rárá ni pé kí o máa yin Ọlọ́run fún oore Rẹ̀ àti ìṣòtítọ́ Rẹ̀. Àmọ́ bí o ṣe ń ronú nípa àwọn ànímọ́ Rẹ̀, ògo Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ síí kún inú rẹ, ọkàn rẹ tí ó fà sí ara rẹ máa bẹ̀ẹ̀rẹ̀ síí fà si yínyin Olórun díẹ̀díẹ̀. Ìyìn jẹ́ ohun tí ènìyàn yàn láti ṣe. Bí o ṣe ń gbé ní iwájú ìdílé rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àti àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, rántí pé wọ́n ń rí bí o ṣe ń ṣe àníyàn tàbí tí ò ń jọ́sìn, bí o ṣe ń káàánú tàbí tí ò ń yìn, bí o ṣe ń kọrin tàbí tí ò ń sunkún. Pinnu lónìí láti yin Ọlọ́run fún ohun tí Ó ń ṣe àti èyí tí Ó máa ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More