Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó so?
Àwọn tó mọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá lè yin fún oore, ìfẹ́, àti ìṣòtítọ́ Rẹ̀. Dáfídì kọrin nípa ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, ó sì búra pé òun á máa ṣe àwọn ojúṣe rẹ̀ láìní àléébù.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Ó yẹ kí ọkàn àwọn ènìyàn Olúwa kún fún ayọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń jọ́sìn Rẹ̀. Òun ni Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ àti Ẹlẹ́dàá tí Ó ún pèsè gbogbo ohun tí áwọn èèyàn rẹ̀ nílò. Pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọpẹ́ fún oore Ọlọ́run, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àti ìṣòtítọ́ rẹ̀ tí kó lópin, Dáfídì fi èrò rẹ̀ láti bu ọlá fún Ọlọ́run hàn nípa fífọ ilé rẹ̀ mọ́, ìgbésí ayé rẹ̀ àti ipò àṣẹ e mọ́ kúrò nínú ìwà ibi èyíkéyìí tó lè ṣèdíwọ́ fún ìyìn Ọlọ́run. Bí onísáàmù náà ṣe ń to àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí kò lè yí padà lẹ́sẹẹsẹ, bẹ́ẹ̀ ni òye rẹ̀ nípa Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i; ìfẹ́ tó ní láti múnú Ọlọ́run dùn nínú ìgbésí ayé rẹ̀ sì wá di edun ọkàn rẹ̀.
Bàwo ni ki n se dáhùnÀwọn onígbàgbọ́ lónìí lè wọlé síwajú Olúwa ní ìgbàkigbà àti ní ibikíbi. Bí o ṣe ń sún mọ́ Olúwa lónìí, fi ìyìn rẹ hàn nípa sísọ àwọn ànímọ́ pàtó rẹ̀ (bí ìwà rere, ìfẹ́, ìjẹ́mímọ́, àti ìdúróṣinṣin Rẹ̀) tí ó fi irú ẹni tó jẹ́ hàn. Tí o bá yin Olórun tọkàntọkàn ó maá ún ìpòùngbẹ wá lati se ìfé Rè ni gbogbo ipò ayé eni. Bi o ń se ń ṣe àṣàrò ìjémímó Rẹ̀, njé o ń dàgbà si nínú èrò àti gbé ìgbé ayé mímọ́ (I Pétérù 1:15-16)? Kíni ohun tí ó ún fà ọ́ jìnà sí áti máa fi gbogbo ọkàn rẹ sin Ọlọ́run? Àwọn nǹkan bí yíyan eré ìnàjú tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tàbí àṣà sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn máa ń ṣèdíwọ́ fún ọ láti yin Olúwa àti láti bọlá fún un. Dákẹ́ nísinsìnyí fún àkókò àyẹ̀wò ara rẹ láti rí i bóyá àwọn apá ibì kan wà nínú ìgbésí ayé rẹ tí Ọlọ́run nílò láti wẹ̀ mọ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More