Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 73 nínú 106

Kíni o sọ?

Àwọn ènìyàn Ọlọ́run yin Ọba Síónì fún ìwà mímọ́, ìdájọ́ òdodo, àti òdodo Rẹ̀. Ó jẹ́ Ọlọ́run olùdáríjini tí Ó dáhùn àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ̀ tí ó bá ronú pìwà dà.

Kíni ó túnmọ̀ sí?

Àwọn orin Dáfídì wọ̀nyí l'áti orin Dáfídì 95 tèsíwájú látí gbé Ọlọ́run ga bí Ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orin Dáfídì ìgbatẹnirò wọ̀nyí ̀kún fún ìṣàkóso ẹgbẹ̀rún ọdún tí Krístì, wọ́n tún ń kéde pé òun ń jọba lórí gbogbo nǹkan lọ́wọ́lọ́wọ́. Àwòrán náà ṣe àpéjúwe ìwárìrì àti ayọ̀ níwájú ìtẹ́ Rẹ̀. Àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìbátan tí ó ṣe pàtàkì pẹ̀lú Rẹ̀ yóò gbé-E ga àti sìn-Ín nípa mímọ̀ àti títọ́jú ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run mímọ́, olódodo, Ó ń fi òtítọ́ bá wa wí, ṣùgbọ́n ó ń na ọwọ́ àánú sí àwọn tí ń ké pe orúkọ Rẹ̀. Ìtẹnumọ́ lórí ìwà mímọ́ ti Olórun ṣe àpèjúwe ìrètí pé àwọn ènìyàn Rẹ tún gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.

Báwo ní ki ṣe dáhùn?

Báwo ni Ọlọ́run mímọ́ ṣe lè fi ààyè gba àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀? Ó máa ń ṣòro fún àwọn onígbàgbọ́ pàápàá láti ní ìjìnlẹ̀ ìwà mímọ́ Ọlọ́run. Bí o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí o sì ń kẹ́kọ̀ọ́, ṣe àkíyèsí àwọn ìlànà Rẹ̀ fún ìwà àti ìhùwàsí rẹ gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Rẹ̀. Àwọn àyípadà ìgbésí ayé wo ni o nílò láti ṣe láti leè bu ọlá àti gbé Olúwa mímọ́ Rẹ̀ ga? Bí o ṣé n gba àdúrà lónìí, yin Jésù gẹ́gẹ́ bíi Ọba gbogbo ayé nípa yìnyín-Ín fún ìwà mímọ́, ìdájọ́ òdodo, àti àánú. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti fún ìdáhùn àwọn àdúrà rẹ.

>

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org