O. Daf 97:1-12

O. Daf 97:1-12 YBCV

OLUWA jọba; ki aiye ki o yọ̀; jẹ ki inu ọ̀pọlọpọ erekuṣu ki o dùn. Awọsanma ati okunkun yi i ka: ododo ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ̀. Iná ṣaju rẹ̀, o si jo awọn ọta rẹ̀ yika kiri. Manamana rẹ̀ kọ imọlẹ si aiye: aiye ri i, o si wariri. Awọn òke nyọ́ bi ida niwaju Oluwa, niwaju Oluwa gbogbo aiye: Ọrun fi ododo rẹ̀ hàn, gbogbo orilẹ-ède si ri ogo rẹ̀. Oju yio tì gbogbo awọn ti nsìn ere fifin, ẹniti nfi ere ṣe ileri ara wọn: ẹ ma sìn i, gbogbo ẹnyin ọlọrun. Sioni gbọ́, inu rẹ̀ si dùn; awọn ọmọbinrin Juda si yọ̀, Oluwa, nitori idajọ rẹ. Nitoripe Iwọ Oluwa, li o ga jù gbogbo aiye lọ: Iwọ li a gbé ga jù gbogbo oriṣa lọ. Ẹnyin ti o fẹ Oluwa, ẹ korira ibi: o pa ọkàn awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ́: o gbà wọn li ọwọ awọn enia buburu. A funrugbin imọlẹ fun olododo, ati inu didùn fun alaiya diduro. Ẹ yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo; ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀.