Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 63 nínú 106

Kíni ó sọ?

Ọlọ́run ni yóò wá gẹ́gẹ́ bí Onidajo lórí ilẹ̀ ayé. Ásáfù ké pé Olúwa kí Ó má ṣe dákẹ́ jẹ́jẹ́ tàbí tí-í rí ṣùgbọ́n kò fí ara Rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Olúwa tí Ó gá julọ

Kí ló túmọ̀ sí?

Àwọn sáàmù wọ̀nyí fi hàn pé ewu méjì ló ń dojú kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run - ọ̀kan láti inú ìjọ àti èkejì láti òde ìjọ. Àwọn onídàájọ́ tó ń ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ń ni àwọn òtòṣì lára dípò kí wọ́n máa ṣe ìdájọ́ òdodo, èyí sì ń mi àwọn ìpìlẹ̀ àwùjọ àwọn Júù tìtì. Sáàmù 83 sọ̀rọ̀ nípa ewu ńlá kan tó ń bọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó ń wá ọ̀nà láti pa orúkọ Ísírẹ́lì rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ewu méjèèjì yìí ló jẹ onísáàmù náà lógún gan-an, ó sì gbàdúrà kíkankíkan nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó sì fi hàn pé Ọlọ́run lágbára láti gbà wọ́n là. Òun nìkan ṣoṣo ló lè ṣe ìdájọ́ òdodo pípé, kó sì ṣàkóso ayé lọ́nà òdodo. Àwọn sáàmù méjèèjì yìí ń tọ́ka sí ọjọ́ tí Kristi yóò padà wá gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ àti Ọba.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ayé tá à ń gbé yìí kún fún ewu. Àwọn ọ̀daràn máa ń jí orúkọ wa, àwọn aṣáájú tó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ kì í jẹ́ ká rí ìdájọ́ òdodo gbà, àwọn apániláyà sì máa ń ba àlàáfíà ọkàn wa jẹ́. Ó lè ṣòro láti máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú ìrètí tó dájú bí ààbò rẹ bá dá lórí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn yàtọ̀ sí Kristi. Jésù nìkan ni Onídàájọ́ àti Ọba tó jẹ́ olódodo, òun nìkan ló lè fún ẹ ní ìbàlẹ̀ ọkàn bó o ṣe ń kojú ìṣòro lójoojúmọ́. Báwo lo ṣe sábà máa ń sọ àwọn àníyàn rẹ fún Olúwa nínú àdúrà? Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè gbàdúrà, àmọ́ Ọlọ́run máa ń kíyè sí gbogbo ohun tó ń kó ìdààmú bá ẹ. Ìṣòro wo ló lè ba àlàáfíà ọkàn rẹ jẹ́ tó yẹ kó o sọ fún Ọlọ́run nísinsìnyí?

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org