Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 64 nínú 106

Kíni ó sọ?

Onísáàmù ń fẹ́ láti wà nínú ilé Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó ń bù kún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé E. Ó bẹ Ọlọ́run pé kó mú àwọn èèyàn Rẹ̀ padà bọ̀ sípò, kó fi ìfẹ́ tí kì í kùnà hàn sí wọn, kó sì gbà wọ́n là.

Kí ló túmọ̀ sí?

Sáàmù ti òní ń fún wa ní òye nípa bí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ṣe yẹ kí wọ́n máa fèsì sí ìwà Rẹ̀. Tí a bá ka àwọn orí yìí láti ẹ̀yìn wá fún wa ní ìrísí tó yàtọ̀. Òǹkọ̀wé Sáàmù 85 mọ rírì ìdáríjì Olórun, ìfẹ́ rẹ̀, àti ìṣòtítọ́ rẹ̀, àmọ́ ó tún mọ̀ pé òdodo Ọlọ́run ń béèrè ìdájọ́ lórí ẹ̀ṣẹ̀. Ìmúpadàbọ̀sípò nílò ìrònúpìwàdà. Ni báyìí, ẹ jẹ́ ká wo Sáàmù 84. Nígbà tí áwọn ènìyàn Ọlọ́run ń gbé ìgbésí ayé wọn láti ṣe ohun tó wu Ọlọ́run dípò kí wọ́n máa ṣe ohun tó wù ara wọn, ó máa ń wù wọ́n gan-an láti jọ́sìn nínú ilé Rẹ̀. Gbígbé Ọlọ́run ga pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mú kí onísáàmù náà ní ẹ̀mí tó jí pépé, ó sì fún un lókun láti gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa. Jíjẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run tó jẹ́ olódodo àti ẹni mímọ́ túmọ̀ sí gbígbé lábẹ́ ìbùkún Rẹ̀ dípò lábẹ́ ìbínú Rẹ̀.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Awújo wa ti din Ọlọ́run ku sí ẹni tó ní àwọn ànímọ́ bíi ìfẹ́, àánú àti inú rere. Ó ti di ohun ìtẹ́wọ́gbà fún àṣà láti ṣẹ̀dá irú Ọlọ́run tí ó fẹ láti gbàgbó níwọ̀n ìgbà tí o bá ti fi àyè gbà ojú-ìwòye ẹlomiran. Àmọ́ ṣá o, ifára dà yìí kò dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn Júù àti ti Krìstẹ́nì. Ìṣòro tó wà nínú èròǹgbà yìí ni pé Ọlọ́run kì í yí padà. Bí Ó ṣe jẹ́ mímọ́ tí Ó sì jẹ́ olódodo lónìí náà Ó wà ní àtijọ́. Ṣé gbogbo ànímọ́ Ọlọ́run ló wà nínú ojú tí o fi ń wo Ọlọ́run, àbí àwọn ànímọ́ tó wù ọ́ nìkan? Gbígbé ní ìtẹríba sí ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ lóòótọ́ ni yóò jẹ́ kí o fẹ́ láti wá ojú rere Rẹ̀, wàá sì máa yin Í pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ yòókù. Bí o ṣe ń ka Bíbélì, bẹ Ọlọ́run pé kí Ó tún èrò òdì ti o ní nípa rẹ̀ ṣe.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org