Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Dáfídì ké pe Ọlọ́run wípé kí Ó fún òun ní ìdáláre àti ìdáàbòbò ní ọjọ́ ògbó rẹ̀.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Jákèjádò àdúrà Dáfídì nínú àyọkà yí ní ìrètí tí ó ní ìpìlẹ̀ wí pé Ọlọ́run yóò mú ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ yóò sì yọọ́ kúrò nínú wàhálà gbogbo. Ìgbẹ́kẹ̀lé Dáfídì pé Ọlọ́run yóò ṣe ohun tí ó tọ́ láti dáàbò bò àti láti dóòlà ẹ̀mí rẹ nínú ewu wá nínú bí ó ṣe ń bá Ọlọ́run rìn títí ìgbé ayé rẹ. Ó kọ́ bí a ṣe ń gbẹ́kẹ̀lẹ́ Ọlọ́run ní ìgbà èwe, ó sì ní ìrírí òdodo Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó sì polongo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi olùgbèjà ní ọjọ́ ògbó rẹ̀. Ìwà Ọlọ́run ti fi hàn pé Ó ṣe è gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà dé ìgbà. Dáfídì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run fún ìdáǹdè, ní ìdánilójú pé kò ní kùnà.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Bóyá o tí lẹ̀ ní ọjọ́ lórí tó láti mọ̀ wípé ìgbé ayé kún fún ìṣẹ́gun àti wàhálà pẹ̀lú. Tí o bá ti jẹ́ ọmọ lẹ́hìn Jésù láti kékeré wá, ronú sì iye ìgbà tí Ó tí ràn ọ̀ lọ́wọ́. Tí o bá sì jẹ́ wípé o ti dàgbà kí o tó wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó ṣeèṣe kí o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí ní ìmọ̀ wípé Ọlọ́run ni ó ṣe é fí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé nínú èyíkéyìí àti ipòkípò tí a bá wà. Láì bìkítà irú ìpele ìgbé ayé tí o wa lọ́wọ́lọ́wọ́, ìdàgbàsókè ìlànà ti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run yóò fún ọ ní ìgboyà nípa ìhùwàsí Rẹ̀ nígbàtí àwọn nkan kò bá lọ bí a ti pinnu. Kí ni ohun tí o dojú kọ lónìí - wàhálà ni tàbí ìṣẹ́gun? Olódodo ni Ọlọ́run, Òun ni ó ṣe é gbé ọkàn lè. Ṣé ìwọ yóò gbẹ́kẹ̀lẹ́ Baba olódodo ọ̀run pẹ̀lú wàhálà rẹ tòní?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More