Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Dáfídì ní kí Ọlọ́run gbà òun l'ọ́wọ́ àwọn ọ̀tá òun àwọn ìkọlù àti ẹ̀gàn ìgbà gbogbo.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Kò sí ìdánilójú àsìkò tí Dáfídì kọ́ orin yí, ṣùgbọ́n ìdààmú rẹ̀ pọ̀ gidigidi dé ibi pé ó dá bíi pé kí ó rì sí abẹ́ omi. Ìdojúkọ àwọn ọ̀tá wọ̀nyí tí wọ́n kórira rẹ̀ ni àìní ìdí, mú kí Dáfídì kọjú sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́. Àdúrà rẹ̀ ṣe àpèjúwe ìrora tí ó jẹ ní kíkún, ṣùgbọ́n bí ó ti ké pé Ọlọ́run fún ìdáláre àti ààbò rẹ, ohun tí ó wuni kan ṣẹlẹ̀ - ó ní ìdánilójú pé ìṣàkóso òun wá ní ọwọ Ọlọ́run. Ìmọ̀ yẹn kún fún ìrẹ̀lẹ̀ níwájú ọlá-àṣẹ Ọlọ́run. Láti ibẹ̀ yẹn, àdúrà ìrora Dáfídì yí padà di orin ìyìn. Ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ yóò wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí ó ń mú ìlérí ṣẹ́.
Báwo ni ó ṣe yẹ kí ń dáhùn?
Nígbàtí ìdààmú bá dé bá wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá máà ń rántí láti ké pe Ọlọ́run. A ó gbàdúrà kíkún nípa àwọn ìṣòro wá kọ̀ọ̀kan, nípa sísọ fún Ọlọ́run ní pàtó ohun tí a fẹ́ kí Ó ṣe. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń dìde kúrò nínú àdúrà wa kí a tó dé ibi ìrẹ̀lẹ̀ bí Dáfídì ti ṣe nínú àyọkà tí òní. Àdúrà gbígbà ni ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ kí a mọ̀ pé Ọlọ́run mọ bí Ó ṣe máà ṣe ètò ayé wá jú àwa fúnra wa lọ. A ní láti jọ̀wọ́ ìṣàkóso wá sílẹ̀ fún Un. Ọlọ́run ti mọ ní kíkún ipò tí o wà kí o tó gbàdúrà, síbẹ̀ nígbàtí o bá wà ní ipò irẹlẹ níwájú Olúwa, ohun kan tí ó lágbára yóò ṣẹlẹ̀ – ìrora ti ara ẹni lè di idi láti yín Ọlọ́run, Ẹnìkan ṣoṣo náà tí ó lè fún ọ ní ìdáláre ati ìtùnú. Ṣé ìwo yóò fi ìrẹ̀lẹ̀ gbá àṣẹ Ọlọ́run l'órí ìgbésí ayé rẹ kí o sì gbẹ́kẹ̀ rẹ le, pàápàá ní àwọn ipò tí ó nira jù lọ?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More