Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Ọlọ́run dìde l'áti dá àbọ̀ bo àwọn aláìlágbára àti àwọn aláìní ní ọwọ́ àwọn ènìyàn ẹlẹ́tàn. Síbẹ̀, ó jọ sí Dáfídì bí ẹni pé a ti gbàgbé rẹ̀ sí inú ìdúró de Ọlọ́run. Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kò le kùnà mú kí ó kún fún orin.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Ìwòye Dáfídì dúró lóríi ibi tí ó fi ìdojúkọ rẹ̀ sí. N'ígbà tí ó tẹ́tí sí ìfọ́nnu àwọn ọ̀tá tí ó sì ń wo ìdojúkọ tí òun là kọjá, ó dàbíi pé Ọlọ́run fi ara pamọ́, Ó wá fií sílẹ̀ láti mú ojú tó èrò àti ìmọ̀lára rẹ̀ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọn n'ígbà tí Dáfídì yàn láti kọ ojú sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìdúró ṣinṣin sí ohun tí Ọlọ́run sọ, ó kún fún ìmọ̀ore tí ó ń ṣàn s'ílẹ̀ fún gbogbo ǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe àti tí yíò tún ṣe. N'ígbà tí ìdojúkọ Dáfídì yí padà, bákan náà ni ìmọ̀lára rẹ̀. Kò di ẹni ìgbàgbé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò leè yẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Rẹ̀ dúró ṣinṣin.
Báwo ni kí ń ṣe fèsì?
A kò lè ṣe aláìmá rí àwọn ìdojúkọ tí ó yí wa ká. Àwọn ìmọ̀lára òdì lè bò ọ́ bíi ìṣàn omi pàápàá n'ígbà tí ó bá dà bíi pé kò sí ohun kan tí ó dára n'íbi yòówù tí o lè kọjú sí. N'ígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dáfídì – dẹ́kun à ún wò kiri kí o sì yàn láti wo òkè. Yálà kí o ja ìjà gbùdù sí ohun tí ò ún là kọ já tàbí kí o fèsì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀. Ó ju kí á ní ìṣèwàhù tí ó dára lọ: níní ìgbẹ́kẹ̀lé tó pé ye nínú Ẹni tí Ó ga jù lọ l'áti bá ọ ṣeé. Ọlọ́run rí ju rògbòdìyàn tí ó ún ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Ọlọ́run lè máa ṣe tí o kò rí? Báwo ni Ọlọ́run ṣe dára sí ọ, pàápàá nínú ìlàkọjá tí ó nira? Kọ ohun mẹ́ta s'ílẹ̀ tí o lè dú'pẹ́ l'ọ́wọ́ Rẹ̀ fún ní báyìí. Lẹ́yìn náà yàn lónìí láti d'ojú èrò rẹ kọ ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìtọ́jú Rẹ̀ sí ọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More