Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Dáfídì bẹ Ọlọ́run pé kó dá àwọn ènìyàn rẹ̀ pa dà sí ipò. kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá wọn.
Kíni ó ìtúmọ̀ sì?
Bí Dáfídì àti Jóábù ń bá àwọn ọ̀tá méjì jà ní ìhà àríwá, Édómù rí àǹfààní láti gbógun ti Júdà láti ìhà gúúsù (Samueli Keji 8; Kronika Kinni 18). Wọ́n ń gbèjà àwọn ènìyàn Ọlọ́run, wọ́n sì ń jà fún ilẹ̀ tí Ó ti ṣè ìlérí fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábráhámù, torí ìdí èyí ìdààmú bá Dáfídì nípa bí Ọlọ́run ṣe gba wọn láyè láti dojú ìjà kọ wọ́n láìròtẹ́lẹ̀ ní àgbègbè tó dà bíi pé ó ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Láàárín àjálù ní orílẹ̀-èdè yí, ní Dáfídì dáwọ́ àdúrà dúró tì ó sì ké pe Ọlọ́run fún ìfẹ́ àti ìṣàkóso Ọba Aláṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Sáàmù tí ó kún fún ìtọ́nisọ́nà(miktam) àti ìdárò yìí jẹ́ apá kan nínú ọ̀nà ti àjọ́ Ìsrẹ́lì fi ń jọ́sìn gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí pé Ọlọ́run ni ìrètí àti olùgbèjà wọn, bóyá wọn ni ìjákulẹ̀ ni tàbí wọn ní ìrírí ìṣẹ́gun.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Sisìn Jésù ni òtítọ́ kò mú wá bọ́ lọ́wọ́ wàhálà. O lè jẹ́ asiwájú - tí ò yọ́ọ̀da ara rẹ láti polongo nínú ilé ìjọsìn tí o sì ń sọ fún àwọn ènìyàn nípa Krístì - tí ó sì jẹ wípé láìròtẹ́lẹ̀ ni ó ní ìdojúkọ ìsọ̀tẹ̀sí láti ọ̀dọ̀ ọmọ rẹ tàbí ìfàsẹ́hìn tí ó pọ nípa ọrọ̀ ajé. Dípò kí ó bèèrè pé "Kílódé?" yí ìbéèrè rẹ padà sí "Tani?" "Tani olùgbèjà rẹ?" Tani ìwọ yóò kọjú sí fún ìrètí? Wàhálà kò lè ṣaláì má wà níwọ̀n ìgbà tí a bá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yì, nítorí náà má bẹ̀rù má sì jẹ́ kí ó bá ọ lójiijì. Mú ìpèníjà tuntun kọ̀ọ̀kan tọ Olúwa lọ, ẹni tí ó fẹ́ràn rẹ tí ó sì jẹ alákòóso ohun gbogbo. O kò leè ní ìrírí ayọ̀ ìṣẹ́gun láì kọ́kọ́ dojú kọ ogun náà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More