Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ǹkan tí ó sọ?
Dáfídì rí ìsinmi fún ọkàn rẹ̀ nípasẹ̀ dídúró de Ọlọ́run, ẹni tí ó tó gbẹ́kẹ̀lé.
Kíni èyí túmọ̀ sí?
Orin yìí ṣe àfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé tí Dáfídì ní nínú Ọlọ́run pàápàá nígbà tí ó ní ìkọlù tàbí tí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀sílẹ̀. Dáfídì gbàgbọ́ nínú ìgbàlà Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó ní ìsinmi nínú Ọlọ́run ní àkókò tí ó ń dúró dè É láti mú gbogbo àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí “dúró” (NKJV) àti “sinmi” (NIV) ni à lè lò fún ara wọn bí a ṣe ǹ wá ààbò nínú Ọlọ́run àti ìṣe Rẹ̀. Irúfẹ́ ìsinmi dá lórí ohun tí a ǹ retí, èyí tó yóò yọrí sí ìrètí tí a lè ṣe àwárí rẹ̀ nípa gbígbékẹ̀lé Ọlọ́run nìkan. Kókó tí Dáfídì ń tọ́ka sí rọrùn: A lè jẹ́rìí Ọlọ́run wípé yóò parí ǹkan tí ó bẹ̀rẹ̀.
Báwo ni kí n ti fèsì?
Púpọ̀ nínú wa ni kò ní lo àwọn ọ̀rọ̀ yí “dúró” tàbí “sinmi” dípò ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó jọ ara wọn. Fún àpẹẹrẹ, a kórìíra láti máa dúró lórí ìlà ní ilé-ìtajà, ṣùgbọ́n a máa ń fojú sọ́nà sí ìgbafẹ́ létí òkun ní àkókò ìsinmi. Orin Dáfídì ti òní rán wa létí wípé nígbà tí ǹkan bá mẹ́hẹ, a lè ní ìsinmi òtítọ́ ní àkókò tí à ń dúró de Ọlọ́run láti parí ètò Rẹ̀. Nígbà tí o bá ṣe àkíyèsí wípé ara rẹ kò lélẹ̀, tọ Ọlọ́run lọ tààrà. Tú ọkàn rẹ jáde fún Un.. Gbogbo ìgbà ló ń tẹti sì ọ; Kò pẹ́ rí bẹ́ẹ̀ni kì í kánjú ó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. O lè ní ìdánilójú nínú Olúwa àti ètò Rẹ̀. Dídúró de ìlérí Rẹ̀ dúró kò rọrùn, ṣùgbọ́n ìrètí tó ń ṣú yọ látinú gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run tó dúró fún. Jókòó kó f'ẹ̀yìn tì. Sinmi. Baba rẹ tí ń bẹ ní ọ̀run ní ohun gbogbo ní ìkáwọ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More