ỌLỌRUN, iwọ ti ṣa wa tì, iwọ ti tú wa ka, inu rẹ ti bajẹ; tún ara rẹ yipada si wa. Iwọ ti mu ilẹ warìri; iwọ ti fọ ọ: mu fifọ rẹ̀ bọ̀ sipò: nitoriti o nmì. Iwọ ti fi ohun ti o ṣoro hàn awọn enia rẹ: iwọ mu wa mu ọti-waini itagbọngbọn. Iwọ ti fi ọpagun fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ, ki a le ma fi i hàn nitori otitọ. Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là; fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si gbohùn mi. Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu. Ti emi ni Gileadi, ti emi ni Manasse; Efraimu pẹlu li agbara ori mi; Juda li olofin mi; Moabu li ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bàta mi si: Filistia ma ho iho ayọ̀ fun mi! Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi nì? tani yio sin mi lọ si Edomu? Iwọ ha kọ́, Ọlọrun, ẹniti o ṣa wa tì? ati iwọ, Ọlọrun, ti kò ba ogun wa jade lọ? Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori pe asan ni iranlọwọ enia. Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin: nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.
Kà O. Daf 60
Feti si O. Daf 60
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 60:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò