Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Dáfídì pòǹgbẹ fún Ọlọ́run bí ènìyàn ti ń pòǹgbẹ fún omi. Ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti gbà á kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́wọ́ àwọn ìkọlù àwọn ẹlẹ́gàn.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Dáfídì ń sá kiri, ó ń sá pamọ́ kiri nínú aginjù. Bó tilẹ̀ ṣe àìní oúnjẹ dídára àti omi, àìní tó ni í lára jù ni àìlè jọ́sìn sí Olúwa nínú Tempili. Ó pòǹgbẹ fún àǹfààní láti kéde ìyìn Ọlọ́run ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́. Ìpòǹgbẹ Dáfídì láti wà níwájú Olúwa ló mú u gbàdúrà, pẹ̀lú ohùn rara fún ìdáàbòbò àti ìtúsílẹ̀. Dáfídì ṣe àwárí ìfọ̀kànbalẹ̀, ìrètí, àti ìsinmi ní iwájú Ọlọ́run pàápàá ní àkókò ìpènijà nínú aginjù.
Báwo ni kí n ti dáhùn?
Kíni àwọn ìrírí ayé kíkorò tó ti mú ọ wà láìní ìrànwọ́? Nígbà tí àwọn àkókò náà bá dé, tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dáfídì kí o sì fi Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ. Ìwàláàyè Rẹ̀ ìsun omi tó tutù àti ibi ìrètí àti ìsinmi. Ohun gbogbo lè dojú rú, àwọn ọ̀tá rẹ pẹ̀lú lè máa dojú ìjà kọ ọ́, àmọ́ ìpèsè Ọlọ́run ju gbogbo rẹ̀ lọ. Ǹjẹ́ o wà lábẹ́ ìkọlù àbí àwọn ẹbí rẹ nínú ìjọ ti pa ẹ́ tì sí ibì kan? A kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀; Ọlọ́run lè mú ìṣẹ́gun wá, nítorí náà sinmi lé e kí o sì ní ìrètí nínú Rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More