Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ǹkan tí ó sọ?
Pẹ̀lú ọkàn tí ó gbọgbẹ́, Dáfídì ké pe Ọlọ́run, ìsádi rẹ̀. Ó gbàdúrà kí Ọlọ́run fikùn ọjọ́ ayé ọba, kí ó paámọ́ pẹ̀lú ìfẹ́ àti òtítọ́.
Kíni èyí túmọ̀ sí?
Ọlọ́run ti fi ìdáhùn sí igbe ẹ̀bẹ̀ Dáfídì fún ìpamọ́ ẹ̀mí rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Ábúsálómù ọmọ rẹ̀ tó dà á. Ní báyìí, Ábúsálómù ti ṣe aláìsí, ọ̀tẹ̀ náà sì ti wá sí òpin. Ará tú Dáfídì ní bákannáà inú rẹ̀ bàjẹ́. Ní ọ̀nà jíjìn réré kúrò nílé àti kúrò ní ibùgbé Ọlọ́run, ó nílò ìpìlẹ̀ tó dúró ṣinṣin láti fi ẹsẹ̀ tì. Ohun kan tí ó mú ìtùnú bá a ní èrò ìwàláàyè Ọlọ́run. Dáfídì mọ̀ wípé olórí àlùfáà nìkan ni ó lè tọ Ọlọ́run lọ níbi Àgọ́ rẹ̀ ìyẹn ní ẹ̀ẹ̀kan l'ọ́dún, síbẹ̀ ó ń pòǹgbẹ láti gbé níbi tí ògo Ọlọ́run wà tí àánú Rẹ̀ sì ń ṣàn sórí àwọn ènìyàn Rẹ̀. Bí Dáfídì ti ń fojú sọ́nà láti padà sí Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ ló ń retí àkókò tí ó ma gbé ní iwájú Ọlọ́run títí láé, ní ìjọsìn sí Ọlọ́run tó wà ní Ọ̀run.
Báwo ni kí n ti fèsì?
A máa ń sábà fi ojú kéré ọ̀pọ̀ ńkan, àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú – pàápàá nígbà tí a bá jẹ àǹfààní wọn lóòrè kóòrè. Bákan náà ni ǹkan ti rí pẹ̀lú ìwàláàyè Ọlọ́run tí kìí fi ènìyàn sílẹ̀. Nítorí ìgbà tó tẹ̀lé ìsọ̀kalẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ní Pentikosti ni a wà yí, àyè gbà wá láti gbé gbogbo ayé wa níwájú Olúwa. Ọlọ́run kìí kàn gbọ́ àwọn àdúrà wa lásán, àmọ́ ìtùnú, àlàáfíà, àti ipá Rẹ̀ ń gbé nínú ọmọ lẹ́yìn Kristi gbogbo. Tani ó máa ń wù ọ́ jùlọ láti wà nítòsí nígbàtí o ní ìpòrúru ọkàn, tí ọkàn rẹ bàjẹ́, tàbí tí gbogbo ǹkan kàn sú ọ? Ṣé ìwàláàyè Ọlọ́run máa ń wù ọ́ ní irú àkókò yí? Gbé ìgbé ayé rẹ pẹ̀lú ìmọ̀rírì wípé ó wà pẹ̀lú rẹ ní ọjọọjọ́. O ní àǹfààní láti rí Aṣẹ̀dá àti Olùgbàlà gbogbo àgbáyé lójú ẹsẹ̀; má ṣe fojú kéré àǹfààní yìí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More