Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 51 nínú 106

Kíni ǹkan tí ó sọ?

Dáfídì yin Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí Olùpèsè ohun dídára gbogbo, àpẹẹrẹ èyí tí í ṣe ìkórè tó pọ̀ jọjọ débi tí ó tó bọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Nínú orin ìkórè yí, Dáfídì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún iṣẹ́ ìràpadà tó fi hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìṣe tó tayọ: bíi ìdáhùn sí àdúrà, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn, pẹlu ìmúgbòròsi ìpamọ́ tó dájú àti ìpèsè pẹ̀lú. Dáfídì rán Ísírẹ́lì létí wípé Ọlọ́run lè ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí nítorí ó ní ágbára ó sì ní àánú pẹ̀lú. Ọlọ́run ló dá àwọn òkè; Ó ń mú kí òkun dákẹ́ rọ́rọ́; Ó ń fa òjò kí ó rọ sórí ilẹ̀ láti mú ìkórè irúgbìn ńlá wá. Gbogbo ènìyàn ló jẹ́ Ọlọ́run ní gbèsè àwọn ìbùkún wọ̀nyí. Ọlọ́run ni Olùgbàlà àti Olùfúnniníyè gbogbo àgbáyé àti wípé ó yẹ fún gbogbo ìyìn àti ìgbẹ́kẹ̀lé ènìyàn gbogbo.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ìhà wo ló máa ń kọ sí nkan nígbà tí àwọn ǹkan ìní rẹ bá joro? Ṣé àníyàn ló máa ń gba ọkàn rẹ kan ní irú àkókò yí bí? Nígbà tí ọkàn rẹ bá dààmú, dárí èrò ọkàn rẹ sí ohùn tí Ọlọ́run ti dá àti èyí tí ó tí ṣe. Ọlọ́run pèsè ohun tí a kò lè ṣe fúnrara wa nípasẹ̀ fífún wá ní àyànfẹ́ ohun ìní Rẹ̀ – Ọmọ Rẹ̀ kan ṣoṣo – nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde ẹni tí a lè fi di ọmọ Ọlọ́run. Ọlọ́run yìí kan náà, Aṣẹ̀dá náà àti Aláṣẹ julọ lórí ohun gbogbo tí ó wá ń pèsè fún wa síbẹ̀. Tí ó bá lè ṣe gbogbo ǹkan wọ̀nyí, dájúdájú ó lè bá àìní wa pàdé ní ọjọọjọ́. Gbẹ́kẹ̀ rẹ lè E; Ó jẹ ẹniti ó tó tán tí ó sì yẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org