Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kín ni ó sọ?
Dáfídì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dáàbò bo ó lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọ. Ọlọ́run ni odi, agbára àti ibi ààbò rẹ̀ ní àkókò ìpọ́njú.
Kín ni ìtumọ̀ rẹ̀?
Dáfídì kọ sáàmù yìí gan-an nígbà tí Míkálì, aya rẹ̀, tí ó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù, ràn án lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin bàbá rẹ̀ tí wọ́n dúró láti pa Dáfídì nígbà tí ó jáde kúrò ní ilé rẹ̀. Àkọlé náà tọ́ka sí pé èyí jẹ́ miktam kan - sáàmù ìtọ́nisọ́nà. Dáfídì kọ àwọn sáàmù mẹ́fà bẹ́ẹ̀ (16, 56-60) nígbà tí ó ń sá fún Sọ́ọ̀lù. Ọ̀rọ̀ tí a pè ní miktam níí ṣe pẹ̀lú kí á tẹ nnkan. Nítorí náa bí ó ti jẹ́ pé ibi kíkà yí jẹ́ àdúrà Dáfídì fúnrarẹ̀ sí Ọlọ́run, nkan kan wà nínú rẹ̀ tí Dáfídì mọ̀ pé ó nílò kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ sí inú àti ọkàn àwọn ènìyàn Ọlọ́run. A kọ ọ́ ní àkókò tí Dáfídì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí sá fún Sọ́ọ̀lù, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan tí a lè rí nínú gbogbo àwọn sáàmù - ó gbàdúrà ní òtítọ́ sí Ọlọ́run Ísraẹ́lì, ó dúró pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún Olúwa Alágbára Jùlọ́ láti ṣe é, ó sì yin ìwà Ọlọ́run nínú èyí tí ó ti rí agbára.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Àwọn òtítọ́ wo ni Ọlọ́run ti tẹ̀ sínú ọkàn àti àyà rẹ nípasẹ̀ ìrírí rẹ? Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni o kọ́ ní àwọn àkókò tí ìnira pọ̀? Àwọn òtítọ́ àti ẹ̀kọ́ yìí gbọdọ̀ wà ní ìrántí kí á sì fi lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. Fi èrò sí ṣíṣe àkọsílẹ̀ nígbà tí o bá ń ṣe àṣarò nínú ọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, tàbí kí o kọ ọjọ́ tí ó jẹ́ sí ẹ̀gbẹ́ ẹsẹ tí ó ní ìtumọ̀ pàtàkì nítorí pé ó tù ọ́ nínú tàbí ó gbà ọ́ ní ìyànjú ní àkókò tí nkan le. Tí Ọlọ́run bá ti fi ọ́ sí ipò adarí tàbi aláṣẹ, wá àwọn ọ̀nà tí o fi lè lo àwọn ẹ̀kọ́ ìyè yìí nínú bí o ti ń darí. O lè fi ohun tí o ti kọ́ lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ níbi tí ìwọ àti ẹbí rẹ ti ń jẹun alẹ́ tàbí nígbà tí ò ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán pẹ̀lú alábàáṣiṣẹ́pọ̀ tàbí ọ iyàrá ẹ̀kọ́ rẹ. Òtítọ́ Bíbélì wo ni o nílò láti fihan ènìyàn kan lónìí?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More