Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 45 nínú 106

Kín ni ó sọ?

Dáfídì fi ẹ̀sùn ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá kan àwọn alákòóso, ó sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìdánilójú ìdájọ́ Ọlọ́run hàn.

Kín ni ó túmọ̀ sí?

Dáfídì lo àwọn àwòrán tí ó ya ni lẹ́nu láti ṣe àpèjúwe ìbínú rẹ̀ lórí ìwà ìrẹ́jẹ tí o ṣe àkíyèsí lọ́dọ̀ àwon alákóso Ísraẹ́lì. Síbẹ̀ kìí ṣe àwọn ẹ̀ṣẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ni ó jẹ́ kí ó pè fún ẹ̀san Ọlọ́run; ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí Ọlọ́run mímọ́ Ísraẹ́lì ni. Dáfídì bínú sí àwọn ohun tí ó tọ́ - ibi àti ìkà. Ó mọ̀ dájú pé Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ìkà lọ́jọ́ kan, ṣùgbọ́n ó pòngbẹ pé kí òdodo Ọlọ́run jọba ní orílẹ̀ èdè rẹ̀ ní àkókó tí ó wà lórí ilẹ̀ Ayé.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Kí ló máa ń mú ọ bínú? Inú wa máa ń sábà ru sókè lórí àwọn nkan kékèèké tí ó bí wa nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ́nì kọ́ọ̀kan ṣùgbọ́n tí a máa ń dákẹ́ lórí àwọn nnkan tí kò mú inú Olúwa dùn. Báwo ni o ṣe lè kọjú lòdì sí ìwà búburú ní agbègbè rẹ àti ní orílẹ̀ èdè wa? Ronú sí dídarapọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ kan tí ó ń mú ìyàtọ̀ wá, bíi kí o yọ̀nda ara rẹ fún iṣẹ́ ní ilé itọ̀jú àwọn aboyún tí ó ní ìṣòro tàbí ẹ̀ka ẹgbẹ́ Àwọn Ìyá Lòdì Sí Mímutí Wa'kọ̀. Máa lọ sí ìpàdé agbègbè níbi tí o ti lè sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ìlànà tí ó tako ẹ̀kọ́ Bíbélì. Máṣe kàn jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan kí o wá gbà pé ayé ti ń d'orí kodò; jẹ́ kí inú bí ẹ sí àwọn nkan tí kò tọ́ kí o sì sọ̀rọ̀ sókè!

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org