Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Onísáàmù yin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí odi agbára fún ìlú Ọba Ńlá náà.
Kí ló túmọ̀ sí?
Bíi ti sáàmù méjì tó ṣáájú, orí yìí náà sọ nípa bí áńgẹ́lì Olúwa ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ásíríà (2 Àwọn Ọba 19). Onísáàmù náà rọ àwọn tó ẹlẹ́rìí rẹ̀ kí wọ́n ṣe àkíyèsí sí ohun tí Ọlọ́run kí wọ́n baà lè sọ ìtàn náà fún ìran tí ó ń bọ̀. Bótilẹ̀jẹ́pé ó ń ṣe ayẹyẹ pé Jerúsálẹ́mù ṣì dúró gẹ́gẹ́ bí ìlú Ọlọ́run, ó tún ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run àti Jésù Kristi, Ọba Ńlá rẹ̀ (Héb. 12:22). Ó fi àlàáfíà rọ́pò ìbẹ̀rù, ayọ̀ rọ́pò ìbànújẹ́, àti ìfẹ́ Rẹ̀ tí kì í kùnà rọ́pò ibi. Àwọn ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun ńlá lórí Ásíríà yìí ṣe àpèjúwe ìṣẹ́gun tí ó ga jùlọ tí Sátánì yóò mú bá àwọn orílẹ̀-èdè tó lòdì sí Ìlú Mímọ́ Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba, àwọn ọmọ ìlú ọ̀run á máa gbé láìsí ewu títí láé.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Kristi, ọ̀run ni ìlú ìbílẹ̀ rẹ (Fílípì 3:20). Àwọn Kristiẹni ní láti máa fi ojú sun ọ̀run nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n ó yẹ kí a mọ̀ nígbà gbogbo pé a kò tíì dé ibẹ̀. Tí gbogbo ìrònú wa bá jẹ́ nípa ti ògo ọ̀run ṣá, a ó pàdánù àwọn ẹ̀kọ́ àti ènìyàn tí Ó fẹ́ kí a pàdé lójú ọ̀nà. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá ń pọkàn pọ̀ sórí gbígbẹ́ inú ayé nìkan, àwọn ìdẹwò inú rẹ̀ lè tàn wá jẹ tàbí kí á rẹ̀wẹ̀sì láti sin Kristi. Máa dúró lóòrèkóòrè láti rò nípa ìgbé ayé ní ọ̀run, yìn Jesu gẹgẹ bíi Ọba ńlá rẹ, kí o sì lọ tọ́ka awọn mììran sí Ìmọ́lẹ̀ ti ìlú ọ̀run yẹn – Jésù Krístì.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More