Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Ọlọ́run bá àwọn ẹni ibi wí ní Ísírẹ́lì, àwọn tó ń rúbọ tí wọ́n sì ń ka òfin Rẹ̀ sókè, ṣùgbọ́n tí wọ́n kórìíra ìtọ́ni Rẹ̀. Ọlọ́run yóò pe ọ̀run àti ayé láti dá àwọn ènìyàn Rẹ̀ lẹ́jọ́.
Kí ló túmọ̀ sí?
Èyí ni sáàmù àkọ́kọ́ nínú sáàmù méjìlá tí wọ́n sọ pé Ásáfù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórí akọrin Dáfídì Ọba kọ. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ásáfù sọ jẹ́ ká rí bí ilé ẹjọ́ ṣe rí, níbi tí Ọlọ́run ti jẹ́ olùfisùn, ẹlẹ́rìí, adájọ́ àti olùgbẹ́jọ́. Ẹ̀sùn méjì ni wọ́n fi kàn án: ìjọsìn tí kò ní láárí àti ìwà àgàbàgebè. Àwọn kan lára àwọn tó pé jọ láti jọ́sìn sọ gbogbo ohun tó tọ́, síbẹ̀ kò sí ohunkóhun nínú ìgbésí ayé wọn tó fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ pé àwọn gbà gbọ́. Wọ́n wá sí iwájú Ọlọ́run bí ẹni pé Ó nílò àwọn ẹbọ wọn dípò kí wọ́n fi tọkàntọkàn rí i pé ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n nílò. Àsọtẹ́lẹ̀ ni ẹsẹ Bíbélì náà tún jẹ́. Ó sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tí Ọlọ́run máa ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní òpin ìpọ́njú ńlá. Títí di àkókò yẹn, àwọn àyànfẹ́ ọlọ́run ń gbé ní àkókò oore ọ̀fẹ́ – ìgbàlà ṣì wà fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ bú ọlá fún Un.
Kí ló yẹ kí n ṣe dáhùn?
Àyoka wá tí òní dá lórí ìpè láti dúró kí a sì ṣe àyẹ̀wò bí a ṣe ń jọ́sin fún Olúwa àti bí a ṣe ń gbé nínú iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni wọ́n so pọ̀ mọ́ ara wọn. Bí ó ṣe ń jọ́sìn nípa lórí bí ó ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ, àti pé ìgbé ayé rẹ yẹ kí o gbé ìjọsìn rẹ lárugẹ. Kíni àwọn ẹ̀sùn tí Ọlọ́run lè fí kàn ọ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ǹjẹ́ ìjọsìn rẹ fún Jésù ti di èyí tí kò ṣe déédéé, tí ó sì kún fún àìṣòdodo bi? Ṣé o ti wá di agbéraga, tó rò pé Ọlọ́run nílò ohun tí ò ń ṣe fún Oun dípò kí o máa wo bó ṣe ń lo iṣẹ́ ìsìn rẹ láti ṣe àtúnṣe ìwà àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Rẹ̀? Ní ọ̀sẹ̀ yìí, máa kíyè sí ní pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ orin tí ó máa ń kọ nígbà ìjọsìn àti ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó o máa ń ní pẹ̀lú àwùjọ kéréje rẹ. Rí i dájú pé o fi àwọn èròjà wọ̀nyẹn lò bí o ṣe ń kúrò ní ilé ìjọsìn tó ò ń lọ síbi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó wà ní ìlú rẹ. Ìjọsìn tòótọ́ máa ń tọ́ka sí Kristẹni to péye.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More