Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Olúwa Olódùmarè, Ọlọ́run Jákọ́bù, jẹ́ ibi ìsádi àtí ìlú olódi fún àwọ́n ènìyàn Rẹ̀. Onísáàmù ṣíwájú àwọn ènìyàn láti yin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Ọba gbogbo ayé.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Àwọn sáàmù yìí ṣe àjọyọ̀ ìṣẹ́gun áńgẹ́lì Olúwa ní orí àwọn ọmọ-ogun Asíríà tí wọn dó tí Jerúsálẹ́mù (2 Àwọn Ọba 19). Hẹsikáyà lọ sí inú tẹ́ḿpìlì ní àṣáálẹ́ ṣáájú ọjọ́ àtakò. Òòyẹ̀ fi ìdáǹdè Ọlọ́run hàn láì jẹ́ pé ẹnikẹ́ni gbé idà sí òkè. Àwọn odi ìlú wọn kì bá tí lè ko ojú ogun Asíríà, ṣùgbọ́n Olúwa Olódùmarè fúnrara Rẹ̀ jẹ́ odi wọn. Ohun tí wọn kàn ní láti ṣe ni, “Dúró jẹ́ẹ́, kí o sì mọ̀ pé Èmi ni Ọlọ́run.” Òru àdúrà kíkan já sí ariwo ayọ̀, àtẹ́wọ́, àti orin ìyìn. Ọlọ́run Jákọ́bù jẹ́ ẹ̀rí ara Rẹ̀ pé Òun ni Ọlọ́run ní orí gbogbo ìjọba ayé, gègẹ́bí Hẹsikáyà ṣe gbàá ní àdúrà.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Báwo ni o ṣe máa ń dáhùn ní ìgbàtí àdojúkọ kan bá ṣúyọ? Ṣé níṣe ni o maá ń sá aré ká láti ró àdojúkọ náà ní agbára bíi ẹnipé ò ń gbé ara dì fún ìjì líle? Sáàmù ti òní ń rán wa ní etí láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ Hẹsikáyà láti dúró, gba àdúrà, kí a sì yìn. Bí ó bá jẹ́ pé ìgbá ìdákẹ́rọ́rọ́ tíí ṣíwájú ìjì ni o wà, pa rọ́rọ́ níwájú Olúwa kí o sí bá A sọ òkodoro ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dùn rẹ. Báwo ni Ọlọ́run yíó ṣe jà fún ọ tó bí o bá lè jọ̀ọ̀wọ́ ohun náà fún Un? Ojúùtú tí yíó mú wá lè má jẹ́ ní kíákíá, ṣùgbọ́n láàrin gbogbo àdojúkọ náà, oó ri àrídájú ọ̀rọ̀ agbára ti Martin Luther pé, “Odi agbára ńlá ni Ọlọ́run wa!”
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More