Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 42 nínú 106

Kí ni ó wà nínú rẹ̀?

Dáfídì gbé gbogbo ìrètí rẹ̀ lé orúkọ Olúwa, ó gbàgbọ́ pé Ọlọ́run yóò mú Doegi wá sí ìparun nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ ibi ju rere lọ. Ọlọ́run yóò kó ìtìjú bá àwọn aṣebi.

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Doegi ará Édómù tí ó jẹ́ olórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Sọ́ọ̀lù sọ fún ọba pé Áhímélékì àlùfáà ti ran Dáfídì lọ́wọ́. Sọ́ọ̀lù pa àṣẹ pé kí Doegi pa àlùfáà 85 àti ìdílé wọn láti gbẹ̀san (1 Sám. 21-22). Nígbà tí Dáfídì gbọ́ ìròyìn yìí, ó kọ Sáàmù 52, ó bẹ Ọlọ́run pé ki Ó gbẹ̀san ibi tí wọ́n ṣe. Ó ṣe pàtàkì kí a kíyèsí i pé kì í ṣe pé Dáfídì fẹ́ gbẹ̀san, àmọ́ ohun tí ó béèrè yìí bá ìwà òdodo Ọlọ́run mu. Orí 53 fi hàn pé Ọlọ́run kóríra àwọn tí ó ń hùwà ibi, yóò sì dá wọn lẹ́jọ́. Lọ́jọ́ kan, gbogbo àwọn tí ó ń hùwà ibi ló máa ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run á sì dé bá wọn.

Kí ni ó yẹ kí n ṣe?

Ó máa ń ṣòro láti mọ bí a ṣe lè gbàdúrà nígbà tí a bá rí bí ìwà ibi ṣe gbòde kan nínú ayé. Gẹ́gẹ́ bíi ọmọlẹ́yìn Kristi, a pàṣẹ fún wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa, síbẹ̀síbẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà nínú wa fi ìbínú òdodo Ọlọ́run hàn sí ohunkóhun tí kò bá jẹ́ mímọ́. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a máa gbàdúrà fún áwọn ọ̀tá Ọlọ́run? O lè ní ìdánilójú pé o ń gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀ nígbàtí o bá gbàdúrà ní ìbámu pẹ̀lú ìwà Rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo; nítorí náà, a lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run mú ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣẹ. Ọlọ́run tún jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú, nítorí náà a lè gbàdúrà fún àwọn ènìyàn kan náà wọ̀nyẹn pé kí wọ́n wá mọ Jésù Kristi, kí wọ́n sì rí ìgbàlà. Ṣé ìwo á fi ọ̀ràn ìgbẹ̀san fún ìwà ibi tí o ti rí àti èyí tí o ti fojú winá rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́? Ìdájọ́ òdodo Rẹ̀ yóò borí níkẹyìn.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org