Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 39 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Onísáàmù náà ṣe àlàyé pé kò sí ẹni tí ó lè pa ọrọ̀ mọ́ lẹ́yìn ikú.

Kì ni ó túmọ̀ sí?

Ẹni tó kọ sáàmù yìí dá àdììtú orin kan sílẹ̀, ó fẹ́ kí olówó àti tálákà jọ ronú lórí òtítọ́ náà pé ènìyàn kò lè san owó ikú tàbí san owó wọ ọ̀run. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò sàn lẹ́yìn ikú nítorí ọrọ̀ tí wọ́n ní nínú ayé yìí. Ìbéèrè tí ó gbé kalẹ̀ nígbà náà ni pé kí ló dé tí ẹnikẹ́ni fi ní láti bẹ̀rù àkókò tí ó nira tàbí àwọn ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ nípa ẹ̀tàn àti riré àwọn ẹlòmíràn jẹ. Eni tó rí towó ṣe àmọ́ tí kò ní òye tí ẹ̀mí yóò di òkùtà níwájú Olúwa. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, ẹni tí ó òye tí Ọlọ́run ọrọ̀ nínú ẹ̀mí tí yóò wà pẹ́ títí, ju ìṣòro ayé yìí lọ.

Báwo ni kí nse dáhùn?

Bíbélì kó sọ wípé níní ọwọ́ kò dára. Àwọn onígbàgbọ́ láti ìran dé ìran ti lo àwọn ohun ìní ti ara wọn fún iṣẹ́ Kristi. Ìṣòro náà ni pé a máa ń fẹ́ láti gbára lé owó dípò Ọlọ́run. Owó tí o fi sí ilẹ̀ ìfọwọ́-pamọ́ kò gbọ́dọ̀ ká ẹ lara ju kí o di aláìnírètí nípa ti ẹ̀mí nígbà tí o bá dúró níwájú Olúwa.. Ṣé bí o ṣe máa kó ọrọ̀ jọ nínú ayé yìí ló jẹ ọ lógún jù ni àbí bí o ṣe ọrọ̀ rẹ jọ ní ìyè àìnípẹ̀kun (Mátíù 6:19-34)? Bó bá ṣé pé Ọlọ́run ti bùkún ọ nní ti owó níní, báwo ni oó ṣe fi dókòwò lórí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́sẹ̀ yìí? Láìka ipò ìṣúnná owó rẹ sí, yan láti fi ìgbàgbọ́ àti ààbò rẹ sí inú Ọlọ́run, kí ó má jẹ́ nínú ohun tí ó pèsè.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org