Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó wà nínú rẹ̀?
Dáfídì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ níwájú Olúwa, ó bèèrè àánú àti ọkàn-àyà tí ó mọ́ lọ́wọ́ Rẹ̀.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Orí yìí jẹ́ kí a mọ bí èèrè ẹ̀ṣẹ̀ ṣe máa tó àti bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti padà ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wòlíì Nátánì sọ fún Dáfídì nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti ikú ọkọ rẹ̀ ló kọ sáàmù yìí (2 Sám. 12). Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, ó sì kábàámọ̀ ohun tí ó ṣe. Ara, èrò inú, àti ẹ̀mí rẹ̀ ti bà jẹ́ gan-an nítorí ọ̀pọ̀ oṣù tí ó fi gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ríronú nípa àánú àti ìdáríjì Ọlọ́run, èyí tí kò ní ẹ̀tọ́ sí, yí ọkàn Dáfídì padà láti má ṣe fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pa mọ́ sí ríronú pìwà dà nínú omijé. Ohun tí ó wù ú jù lọ ni pé kí ó wà ní mímọ́ níwájú Olúwa kí ó lè tún rí ayọ̀ wíwà níwájú Ọlọ́run, kí ó sì máa yìn Ín nígbà gbogbo.
Kí ni ó yẹ kí n ṣe?
Bí ìdẹwò bá gbé àwòrán ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn wá sọ́kàn wa, èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú wa ló máa sáré lọ sí ibòmíràn. A kì í fi bẹ́ẹ̀ mọ ibi tí ìṣẹ́jú díẹ̀ tí a bá ṣe àìgbọràn lè yọrí sí. Ẹ̀ṣẹ̀ tí a bá dá máa ń mú inú bí Ọlọ́run, ó máa ń dun àwọn ẹlòmíràn, ó sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Ṣé ìwà kan wà tí o ti ń fi pa mọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé rẹ tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan tí o ti dá tẹ́lẹ̀ tí ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀? O kò lè fi wọ́n pa mọ́ fún Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà á tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì nínú ẹsẹ Bíbélì tí a kà lónìí? Ẹ jẹ́ kí Olúwa mọ ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì rí ayọ̀ tí ó wà nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí a mú padà bọ̀ sípò, kí ẹ sì ní ọkàn tuntun láti máa yìn Ín, kí ẹ sì máa sìn Ín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More