ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀. Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla. A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀. Sa wò o, awọn ọba pejọ pọ̀, nwọn jumọ nkọja lọ. Nwọn ri i, bẹ̃li ẹnu yà wọn; a yọ wọn lẹnu, nwọn yara lọ. Ẹ̀ru bà wọn nibẹ, ati irora bi obinrin ti nrọbi. Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi. Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai. Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ. Ọlọrun, gẹgẹ bi orukọ rẹ, bẹ̃ni iyìn rẹ de opin aiye: ọwọ ọtún rẹ kún fun ododo. Ki òke Sioni ki o yọ̀, ki inu awọn ọmọbinrin Juda ki o dùn, nitori idajọ rẹ. Rìn Sioni kiri, ki o si yi i ka: kà ile-iṣọ rẹ̀. Kiyesi odi rẹ̀, kiyesi ãfin rẹ̀ wọnni; ki ẹnyin le ma wi fun iran atẹle nyin. Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú.
Kà O. Daf 48
Feti si O. Daf 48
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 48:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò