Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kini ó ṣọ́?
Òǹkọ̀wé yí kọrin nípa ọlá àti ẹwà ọba àti ẹwà ìyàwó rẹ̀
Kíni ó túmọ̀ sí?
Orin yí ṣe àpèjúwe ìgbéyàwó ọba alágbára tí ó sì jẹ ólufọ́kànsìn kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé a kò mọ àkókò gan-an tí a kọ́ tàbí ọba tí ó ń tọ́ka sí, àpèjúwe náà ń tọ́ka sí Sólómọ́nì tàbí Hesekáyà. Nítorí wípé ó fẹ́ràn òdodo ó sì kórira ìwà ìkà, ọba yí yíò rí ojú rere Ọlọ́run àti pé àwọn ènìyàn yíò rántí rẹ̀ sì rere Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe tóbi pàápàá, ìjọba rẹ̀ ni àsopọ̀ pẹ̀lú Jésù Fúnra rẹ̀ bí oǹkọ̀wé Hébérù, tí ló àwọn ẹsẹ díẹ̀ láti inú Orin yí nípa títáyọ́ Kristi ju àwọn tó kù (Hébérù 1:8-9).Jòhánù pẹ̀lú ṣe àmúlò ibi kika nípa Olùgbàlà yí nínú ìwé Ìfihàn láti ṣe àpèjúwe bíbọ̀ Kristi fún ìjọ Rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ṣe fí aṣọ ṣe ara rẹ lọ́ṣọ́ láti tẹ̀ ọkọ rẹ lọ́rún, ìjọ náà ni láti fí òdodo wọ ara rẹ nígbà tí Jésù Ọba bá wá pade ìyàwó Rẹ̀ (Ìfihàn 19:6-8)
Báwo ló ṣe yẹ kí ń dáhùn?
Ìjọ Jésù Kristi jẹ àkójọpọ̀ gbogbo ènìyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ fún ìgbàlà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n láti ọjọ́ pípẹ́ wá. Fún àwa tí a wá láàyè tí a sì ń tọ lẹhin loni, àwọn yí ni àwọn ọjọ́ ipálẹ̀mọ́ wá gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Kristi. Ipò tí ìjọ wá lápapọ̀ dúró lórí ìjọ kọ̀ọ̀kan ni agbegbe rẹ, èyí tí ó tún dá lórí ìgbé ayé ìgbọràn ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan. Tí Jésù bá dé loni, ṣe inú aṣọ àkísà ló máa tí bá ọ ní tàbí inú òdodo Rẹ̀? Báwo ni ó ṣe ń gbaradì láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú kí ìjọ rẹ dúró gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Kristi ọlọ́lá? Pinnu láti má ṣe fí ọjọ kan ṣòfò lórí ìgbáradì bí a ṣe ń retí ípádábọ́ Rẹ̀
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More