Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ló sọ?
Olùkọ̀wé yìí rántí bí Ọlọ́run ṣe mú kí àwọn bàbá wọn gbilẹ̀ ó sì ṣọ̀fọ̀ pé Ọlọ́run kò bá àwọn lọ jagun mọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò tíì gbàgbé orúkọ Rẹ̀.
Kí ló túmọ̀ sí?
Wọ́n lo sáàmù yí níbi ìjọ́sìn àpéjọpọ̀ tí wọ́n fi ṣọ̀fọ̀ ìjákulẹ̀ tí wọ́n bá pàdé láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn. À ń kó àwọn ènìyàn Ọlọ́run láyà jẹ bí ó tilẹ̀ ṣe pé wọ́n ń gbé orúkọ Olúwa ga dípò àwọn òrìṣà. Ìjẹ́wọ́ ódodo wọn sí Ọlọ́run fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí á ti kọ sáàmù náà nígbà ayé Hesekáyà Ọba. B'ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti mú Júdà kúrò lọ́wọ́ àwọn òrìṣà ilẹ̀ òkèèrè tó sì ti tún mú ìjọsìn Ọlọ́run Olódùmarè padà bọ̀ sípò já'kè já'dò orílẹ́ èdè náà, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Àsíríà ń kó ìjọba rẹ̀ lọ láìdábọ̀. Ohun tí a tún lè fi wé ìpinnu oní sáàmù láti jẹ́ olódodo sí Ọlọ́run ni ìgboyà ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ pé kí Ọlọ́run tají, kí ó dìde, kí ó sì ran àwọn lọ́wọ́ – ẹ̀bẹ̀ tí ó dá lé ìfẹ́ Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ tí kìí kùnà.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Níní ìṣẹ́gun lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti di ayè rẹ nígbèkùn fún ọ ní òmìnira. Síbẹ̀, ìṣẹ́gun nínú nnkan tí ẹ̀mí kò yẹ kí ó fún wa ní ìmọ̀lára ẹ̀tọ́ níwájú Ọlọ́run. O ti wá di pé kí a máa retí ìbùkún aláìnídiwọn Rẹ̀, bíi ìgbà tí àwọn ọmọ ilé-ìwé ti ń gba èrè nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tí olùkọ́ wọn ní kí wọ́n ṣe. Ṣé o pinnu láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, láìbìkítà ohun tí y'Ó gbà láàyè nínú ayé rẹ, tàbí ṣé ìgbọràn rẹ wà ní ìsopọ tààrà sí àwọn ìbùkún Rẹ̀ nìkan ni? Gbàdúrà pẹ̀lú ìgboyà lórí àwọn àdójúkọ tí o ní, kí o sì pinnu láti fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run nìkan(Jobu 13:15)pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí a lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ́ ògidì ( Peteru Kinni 1:6-7).
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More