Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Òǹkọ̀wé náà rántí bí ó ti ń fi tayọ̀-tayọ̀ ṣíwájú nípa kíkó àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ sí ilé Ọlọ́run. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn, ó rán ara rẹ̀ létí láti ní ìrètí nínú Ọlọ́run kí ó sì yin Ẹni tí Ó ǹfi ife darí rẹ̀.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Sáàmù 42, Sáàmù yìí ní àkọ́kọ́ tí àwọn ọmọ Kórà kọ, láti sàmì ìbẹ̀rẹ̀ Ìwé kejì nínú Sáàmù. Àwọn iran Kórà borí i ìṣọ̀tẹ̀ tí a mọ àwọn baba ńlá wọn fún. Wọ́n fi òdodo darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú ìjọsìn wọn nínú Tẹ́mpìlì (Númérì 16). Òǹkọ̀wé náà jìnà sí Jerúsálẹ́mù, à ń fi ìyà jẹẹ́ nínú ara a sì ń pẹ̀gàn rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn aláììwà-bí-Ọlọ̀run. Èrò tí ó jẹ́ lọkàn ní láti padà sí Tẹ́nìpìlì tí ó sì dárí rẹ sì ipasẹ̀ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìfẹ́ Ọlọ́run gbé e ró ni ọjọ́ náà ó sì fún ń ní orin ní ọ̀gànjọ́. Ìpohùnréré yìí dúró lórí ìdí kan tí ó fún ní ìrètí pé yóò tún rẹ́rìn-ín lẹ́ẹ̀kansi – Olùgbàlà rẹ̀, Àpáta rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Irú ìyípadà kan tó lé tí ó sì lè mú kí á ní ìmọ̀lára ìtara tí kò dúró déédéé, ó sì lè mú àkókò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn wá. Nígbà míràn, ó wù wá ki àyípadà dé bá ohun tí à ń là kọjá, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi àyè gba kí ó máa ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́. Kíni ohun tí o lè ṣe nígbàtí ìgbé ayé bá fi ọ́ sí inú òkùnkùn tàbí àìbalẹ̀ ọkàn? Ṣé àwárí ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ jáde. Bíbélì jẹ́ atọ́ka ọ̀nà, Òun darí èrò wa kí a má bàa ṣìnà nípa ti Ẹ̀mí. Ó ń rán wa létí nípa Ọlọ́run àti bí Ó tí ṣe olótítọ́ sì wá láti ìgbà pípé sẹ́hìn. Ǹjẹ́ ìrètí rẹ ti sáki rí? Ní ìrètí nínú Ọlọ́run; Ìwà Rẹ̀ kò yípadà rárá nínú onírúurú àyídáyidà ayé yìí tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí wa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More