Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 33 nínú 106

Kíni ó sọ?

Bí àwọn ọ̀tá Dáfídì ṣe ń dúró de kí ó kú sí inú àìsàn, tí àwọn ọ̀dàlẹ̀ ọ̀rẹ́ já kulẹ̀, Dáfídì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa láti fi àánú gbé e ró, kí Ó sì mú u padà bọ̀ sì ípò.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Láti ní òye sáàmù yìí, ó jẹ dandan làti mọ bí a ṣe kọ́. "Ẹnikan" tí ó jẹ "ọrẹ tímọ́tímọ́" tí Dáfídì sọ nípa rẹ̀ nínú àyọkà yí ni ọmọkùnrin rẹ Ábsálómù àti Àhítófélì (tó kọ̀ ẹ̀hìn sí Dáfídì lẹ́yìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Báṣébà àti ìṣekúpa Ùráyà). Àhítófélì jẹ́ bàba-bàbá Báṣébà, ṣùgbọ̀n ìkórira ọkàn Ábsálómù fún bàbá rẹ̀ díjú díẹ̀. Dáfídì kò ì tíì fì ìyà jẹ ọmọ rẹ̀ Ámnónì lórí ìfipábánilòpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àbúrò Ábúsálómù tí ó jẹ obìrin. Nígbàtí Ábsálómù pa Ámnónì, Dáfídì yẹra fún ùn pátápátá fún àìmọye ọdún, eléyìí mú ìkorò-ọkàn bá Ábsálómù, ó sì fẹ́ẹ́ gbẹ̀san. Dáfídì ní ìmọ̀lára òkodoro àsọtẹ́lẹ̀ Nátánì pé idà kò níí kúrò ní ilé òun láí. Ó ti lè lérò pé òun kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ làti ṣe ìdájọ́ òdodo látàrí àwọn irúfẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kan náà tí òun pẹ̀lú ṣẹ̀. Bíótilẹ̀jẹ́pé Dáfídì ti dúró déédéé pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́yìn ìgbà tí ó ronúpìwàdà, àwọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tọ̀ọ́ lẹ́hìn, wọ́n sì fa ẹbí rẹ̀ ya.

Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?

Ó di dandan kí Olúwa dáríjì wá bí a bá ronúpìwàdà tọkàntọkàn, ṣùgbọ́n àwọn àbájáde rẹ̀ a máa lágbára kọjá ibi tí ó yẹ nígbà míràn. Bí ó bá jẹ́ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lò ń jẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí o sì wá àwọn tí o tí palára kàn. Ronú lórí ìkìlọ̀ tó wà ní ídí àyọkà yìí – ìdẹwò tó ń tàn ọ́ lónìí lè ṣe okùnfà ohun tí apá kò ní ká ní ọjọ́ ọ̀la. Ṣé ó yàn láti ronúpìwàdà kí èró ẹ̀ṣẹ̀ tó di ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ọ lọ́wọ́?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org