Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò gbé ọkàn wọn lé Olúwa bí Dáfídì ṣe sọ̀rọ̀ sókè nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu, ìfẹ́, àti òtítọ́ Olúwa – ìrètí rẹ̀, ìrànlọ́wọ́, àti ìdáǹdè.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà ìṣọ̀tẹ̀ Ábúsálómù la kọ àwọn Sáàmù méjèèjì yìí nígbà tí Dáfídì jìyà nínú ara fún àbájáde ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ́ pẹ̀lú Bátíṣébà. Ó jọ pé, fún Dáfídì nǹkan kò lè burú jù bí ó ti wà lọ. Kàkà kí Dáfídì sinmi àròyè ṣíṣe nìkan, ó kúkú gbìyànjú láti dákẹ́ jẹ́ẹ́ pátápátá láti rí i dájú pé òun kò yọ̀, òun kó sì ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Ìgbìyànjú rẹ̀ láti dákẹ́ jẹ̀ẹ kùnà bí ó tí ń tú àwọn ẹdùn rẹ̀ jáde, àwọn ìbéèrè, àti Ìjẹ̀wọ́ rẹ̀ sí Olúwa. Irú ìgbónára bẹ́ẹ̀ mú kí Dáfídì mọ rírì gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún láti ẹ̀yìn wá, èyí sì mú kí ó mọ nǹkan tí ohun tí ìjọsìn dá lé lórí. Ó ní ìgboyà pé àwọn mìíràn yóò tún gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbàtí òun bá sọ̀rọ̀ ní gbangba nípa ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run. Ọlọ́run tó ràn án lọ́wọ́ nígbà àtijọ́ ni Ọlọ́run tó fi ààyè gba ipò tí ó wà nísinsìnyí. Gbogbo ìrètí Dáfídì fún ìdáǹdè wà nínú Rẹ.
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Nígbà gbogbo a máa ń dákẹ́ sí àwọn nǹkan tí ó kàn wá gbọ̀ngbọ̀n. Àwọn àròyé àti àwọn èrò búburú a máà tú jáde láti inú wa bi ìkòkò iná tó fọ́, nígbà tí ògidì ìyìn fún Olúwa dì nǹkan tí a bò mọ́ra. Tí a ó bá jẹ́ olóòótọ́ nípa ìdí tí èyí fi ń ṣẹlẹ̀, a ó gbà pé a gbá ojú mọ́ àwọn ohun tí kò lọ déédéé ju ìfẹ àti àánú Ọlọ́run lọ. Kíni àwọn ohun wọnnì tí o sọ̀rọ̀ sókè lé lórí jùlọ nínú ọ̀sẹ̀ yí? Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ fa àwọn ènìyàn sí agbo Krístì, tàbí a ha le kà wọ́n sí ẹ̀ṣẹ̀ bí? Máse dúró dé àkókò tí àyípadà rere bá dé bá ọ kí ó tó mọ bí a tí ǹ yín tí a aì ń jọ́sìn fún Olúwa ní gbangba. Ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tí Ó tí ṣe láti ẹ̀yìn wá yóò mú kí àfojúsùn rẹ dára síi lóri ohun tí Ó lè ṣe fún ọ nísinsìnyí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More