Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 31 nínú 106

Kíni ó sọ?

Ìbáwí tí Ọlọ́run fún Dáfídì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mú ẹ̀rí ọkàn tó ń dá a lẹ́bi àti ìrora tó ń bá a fínra wá, èyí ló mú kí Dáfídì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì dúró de ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Ìwà àgbèrè tí Dáfídì hù sí Bátíṣébà àti pípa tó pa ọkọ rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ yọrí sí ìparun rẹ̀, èyí ló mú kó kọ àwọn Orin Dáfídì fún ìrònúpìwàdà (6, 32, 38, àti 51). Àpèjúwe tí wọ́n ṣe nípa bí ara Dáfídì ṣe rí nínú àwọn àyọkà yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé adẹ́tẹ̀ ni Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ló ń fa gbogbo àìsàn, síbẹ̀ orí yìí fí ìdí rẹ múlẹ́ dájú pé ní ìgbà míràn Ọlọ́run máa ǹ fí ìpẹ̀kun ọwọ́ lile mú kí áwọn ọmọ Rẹ̀ láti dá wọn mọ fún àṣìṣe wọn. Ìtara àti ìbànújẹ́ ọkàn Dáfídì jẹ nǹkan tó fà ìrora gẹ́gẹ́ sí agọ́ ara Dáfídì. Ọwọ́ líle tí Ọlọ́run fí bá Dáfídì wí ṣe okùnfà bí Dáfídì di àláínírètí tí ó sì fà ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Báwo ní ó ṣe yẹ kí ń dáhùn?

Àìsàn àti ìrora ọkàn àwọn nǹkan tí ènìyàn ní láti lá kọjá nítorípé ẹ̀ṣẹ̀ tí gbá ayé kan. Nígbà míràn ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run lè jẹ́ kí wàhálà wọlé sí ìgbésí ayé rẹ bí ọ̀nà láti jeki ó kíyèsara rẹ bí o kò bá kíyèsí ìbáwí Rẹ̀. Ló àkókò díẹ̀ láti ronú nípa àwọn nǹkan tó ń kó ìdààmú àti ìbànújẹ́ ọkàn bá ọ lónìí. Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa, kí ó sì sọ fún un pé kí ó fi hàn wá bóyá èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn jẹ́ ìbáwí Ọlọ́run. Má ṣe dúró dìgbà tí Ọlọ́run bá mú ọ dé ibi ìpayà. Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kí ẹ̀rí ọkàn rẹ mọ́ kó o sì máa bá ìgbésí ayé rẹ lọ.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org