Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Máṣe ìkanra nígbàtí àwọn ènìyàn búburú bá ṣe àṣeyọrí, sùgbọ́n ṣe rere. Gbẹ́kẹ̀le kí o sì yọ̀ nínú Olúwa. Dúró jẹ́ kí o sì fi ọ̀nà rẹ lé lọ́wọ́, kí o dúró pẹ̀lú sùúrù nítorí Ó ńgbé àwọn olódòdo dúró.
Kíni ó túmọ̀ sí?
Dáfídì ṣe alábàápín ọgbọ́n àgbàlagbà kan tí ó ti kíyèsí àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn olódòdo. Kò dá bí ìwé Jóòbù, Orin yìí kò sọ̀rọ̀ nípa, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ibi?” Dípò bẹ́ẹ̀, Dáfídì dojúkọ àkíyèsí rẹ̀ sí ohun kanṣoṣo tí àwọn olódòdo lè ṣàkóso - ìdáhùn wọn sí pé ibi yíò máà tèsíwájú ní àgbáyé. Ọmọ Ọlọ́run tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé máa ń rí ìdùnnú nínú ohun tí ó mú inú Rẹ̀ dùn, èyí tó máa ń mú kí ìlépa ẹni bá ìfẹ́ Olúwa mu. Olódodo kò nílò láti pète-pèrò láti rí ààbò; wọ́n lè gbé láàrin ohun tí Ọlọ́run ńpèsè, wọ́n mọ̀ pé yóò tọ́jú gbogbo àìní wọn. Àsìkò àwọn ènìyàn búburú yóò ré kọjá tó bá yá. Ní ọjọ́ kan Ọlọ́run yóò san fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bíi isẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ènìyàn búburú ni yóò mú kúrò pátápátá níwájú Rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn oníwà-bíi-Ọlọ́run yóò gbádùn ojúrere àti ìbùkún Olúwa fún ayérayé.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Ó jẹ́ ìbànújẹ́ láti máà wo bí ibi tí ń pọ̀ sí jù ìwà rere lọ ti orílẹ̀-èdè wa sì ń díbàjẹ́ sì. Ọlọ́run pe àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ ti ẹnìkọ̀ọ̀kán ju àwọn ẹ̀bẹ̀ tàbí àwọn lẹ́tà sí àwọn aṣòfin. Wo Orin Dáfídì 37 lẹ́ẹ̀kansi; fi gègé yíká tàbí ṣe àfihàn àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tí Dáfídì ló: ìgbẹkẹ̀lé, ìdùnnú, ìfarajìn, dúró jẹ́, ṣe rere, dúró, àti pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́ (NIV). Pẹ̀lúpẹ̀lù ṣàkíyèsí ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe: máṣe ìkanra, yàgò fún ìbínú, yípadà kúrò nínú ìbínú àti ibi. Èwo nínú ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ ibi ágbára rẹ̀, èwo ló jẹ́ agbègbè àìlera nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣáájú kí o tó lọ sórí ayélujára láti sọ̀rọ̀ nípa gbogbo àṣìṣe tó wà lágbayé, béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run kí Ó sọ fún o nípa bí ìwọ tìkálárarẹ kò ti ní ìgbẹkẹ̀lé tàbí ní ìdùnnú nínú Rẹ̀. Báwo lo ṣe máa fi gbogbo ọkàn rẹ hàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóni?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More