Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Ẹni burúkú kì í bẹ̀rù Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ ara wọn tàbí kí wọ́n kọ ohun tí kò tọ́ sílẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kò kùnà pèsè ààbò fún àwọn aadúróṣánṣán í ọkàn tí ó mọ̀ ọ́n.
Kí ni itúmọ̀ rẹ́?
Àyọkà òní ṣe àfihàn ìyàtọ̀ tó wà láàrin àwọn tí o mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ẹnití a ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí "búburú" fi ìgbéraga gba ìwà àléébù rẹ̀ bí ènìyàn. Níwọ̀n ìgbà tí kò jẹ́wọ́ Ọlọ́run tàbí òfin Rẹ̀, àwọn ìlànà kan ṣoṣo fún ìwà rẹ̀ ni èrò àti ìfẹ́ ara rẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ní ìrọ̀rùn - kò sí ohun tí ó dára tàbí àṣìṣe nínú ìrònú rẹ̀. Ní ìdàkejì, Dáfídì ṣàpèjúwe ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bíi "adúróṣánṣán nínú ọkàn," tí èrò àti ìṣe rẹ̀ wà lábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run. Ẹni yìí gba ìṣe Ọlọ́run mọ́ra, ó fara mọ́ ìfẹ́ àti òtítọ́ Rẹ̀ fún ìwàláàyè òun tìkara rẹ gan-an.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Ojú tí o fi ń wo Ọlọ́run ló máa pinnu bí o ṣe ń ronú àti bí o ṣe ń hùwà. Ronú sí ìhùwàpadà rẹ sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmó ṣe lè yàtọ̀ bí ìrònú rẹ àkọ́kọ́ bá jẹ́ lóríi ìwà Ọlọrun tí kò lè yí padà. Njẹ a ti ṣẹ̀ ọ́ rí bí? Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ rántí pé Ọlọ́run máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Wo àwọn ìjákulẹ̀ àìpẹ́ yìí nípasẹ̀ ìmọ̀ pé Ó jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ìgbà, kódà nígbà tí a kò bá tíì rí i. Tí o bá ti ń tiraka pẹ̀lú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ - wo ìfẹ́ rẹ̀ tí kò kùnà láti rí ìdáríjì gbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, síbẹ̀síbẹ̀, o yàn láti kọ àṣẹ Ọlọ́run lórí èrò àti ìṣe rẹ kọ̀ọ̀kan, oó pàdánù ààbò àti ìpèsè tí Ó ń pèsè. Kí ni o ò fi ara mọ́ lónìí - ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tàbí Olúwa olódodo?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More