Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Dáfídì bèèrè lọ́wọ́ Olúwa láti da ìparun àti ìtìjú sí orí àwọn tí ó ti fi ibi san ire rẹ̀ padà. Ó fojú sọ́nà láti gbóríyìn fún Olúwa ní gbangba fún ìdáláre tí ó rí gbà.
Kí ni itúmọ̀ rẹ́?
Orin Dáfídì 35 jẹ́ sáàmù ìpè fún àjálù ibi nínú èyí tí Dafidi kò kàn bẹ Ọlọ́run láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n bákannáà kí Ó pa wọ́n run pátápátá. Àgbàlá ọba Sọ́ọ̀lù kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké wúyẹ́wúyẹ́ nípa Dáfídì ní etí Sọ́ọ̀lù. Àwọn ọkùnrin tí ó ti pè ní ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ wọ́n sì ń mú ìdààmú rẹ̀ pọ̀ si. Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé ìmọ̀lára Dáfídì jẹ́ ti ènìyàn ṣùgbọ́n ó bá ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mu fún àwọn tí wọ́n kọ ète rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí Dáfídì jẹ́ ọba ẹni àmì òróró Ọlọ́run, ó gbé àwòrán ìtọ́ka sí ète Ọlọ́run fún ọjọ́ iwájú Israẹli. Nítorí náà, èyí jẹ́ ẹ̀bẹ̀ fún orúkọ Ọlọ́run àti ìdí láti gbé e lárugẹ. Dáfídì tọ́ka sí ìwà ìrẹ́jẹ sí Ọlọ́run òdodo rẹ̀, ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run pé àwọn ẹni búburú kò ní borí àwọn olódodo.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, ó ṣe é ṣe kí o ṣeré "ṣòfófó" tàbí "ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀," eré nínú èyítí ẹnìkan á sọ̀rọ̀ wúyẹ́ sí etí ẹnìkan títí yóò fi yípo, ṣùgbọ́n tí yóò ti sọ ìtumọ̀ rẹ̀ nù nígbàtí ó bá bá dé ọ̀dọ̀ ẹnití ó gbẹ̀yìn. Ohun kannáà yìí ń ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí aye. Kò sí iye wákàtí tí o lò láti sọ̀rọ̀, tẹ ọ̀rọ̀ sínú afẹ́fẹ́, kí ó ránṣẹ́ fàyè rí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeéṣẹ láti ṣe àtúpalẹ̀ ìbàjẹ́ ọ̀rọ̀ burúkú. Pẹ̀lú, tí o bá jẹ́ kí ohun tí àwọn ẹlòmíràn ńsọ nípa rẹ borí ọkàn rẹ, ó ṣeéṣe kí wọ́n ṣí ọ lọ́kàn kúrò nínú ète Ọlọ́run fún ọ. Ogun ẹ̀mí ṣe é jà dáadáa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ẹ̀mí - àdúrà àti àkókò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Báwo ni àdúrà rẹ fún ìdáàbòbò Ọlọ́run ṣe nílò láti dún bíi Dáfídì nínú àyọkà òní? Ǹjẹ́ ọkàn ń ru sókè fún ìdájọ́ tàbí ẹ̀san? Ǹjẹ́ ò ń ṣàníyàn nípa orúkọ rẹ tàbí ti Ọlọ́run? Wá Ìwé Mímọ́ kí o lè gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn náà kí o sì fi ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More