Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 27 nínú 106

Kí ni ó sọ?

Dáfídì gbóríyìn fún Olúwa pé ó gbà á lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀rù àti ìpọ́njú rẹ̀

Kí ni ó túmọ̀ sí?

Dáfídì kọ sáàmù yìí lẹ́yìn tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ tó níye lórí nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run. Ó bẹ̀rù Sọ́ọ̀lù tóbẹ́ẹ̀ tí ó sáré lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá fún ààbò dípò kí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa (1 Sam. 21). Ó rí ara rẹ̀ ní ipò ewu nínú ibùdó àwọn ọ̀tá àti ní ẹ̀yìn odi ìfẹ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí ó sá àsálà nínú ewu yìí tán, ó hàn sí Dáfídì bí òun ṣe jẹ́ òmùgọ̀ tó. Ó fi ohun tí ó kọ́ lé ìran tí ó ńbọ̀ lọ́wọ́: Ọlọ́run rí ìṣòro àwọn olódodo, ó gbọ́ àdúrà wọn, ó sì sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́. Ìgbé ayé kò ní sàì ní wàhálà, ṣùgbọ́n Olúwa lè gbàlà, kódà ó rán àwọn angẹli Rẹ̀ láti pàgọ́ yí àwọn olódodo ká. Dáfídì kún fún ìyìn sí Olúwa, ibi ààbò òtítọ́ rẹ̀ kan ṣoṣo.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Ẹ̀rù lè mú kí a ṣe awọn ohun aláìní ọgbọ́n nínú. Bótiwù kí igbesi aye dàbíi pé kò ní ìṣàkóso, ó léwu ní gbogbo ìgbà láti fi àkóso sí ọwọ́ ara ẹni. Ní àkókò wo nínú ayé rẹ ni ìbẹ̀rù ti mú ọ ya ibòmíràn fún ààbò? Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú ọ lu àlùyọ lẹ́yìn tí o ti ṣe ìpinnu òmùgọ̀? Àwọn ẹ̀kọ́ tí o ti kọ́ ní àwọn àkókò yẹn ṣe pàtàkì jù ki ó fi pamọ́ lọ. Tani Ọlọ́run ń fẹ́ kí o sọ fún nípa bí Ó ṣe dásí ọ̀rọ̀ ayé rẹ? Ẹnìkan tí ó wà ní àyíká ipa rẹ nílò láti gbọ́ pé Ọlọ́run rí àwọn ìṣòro rẹ̀ Ó sì lè gbàá. Ṣé oó sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí o ti kọ́ kí o sì yìn Ọlọ́run fún ìṣòtítọ́ Rẹ̀ lónìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org