Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kí ni ó sọ?
Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run ní ìdí láti yọ̀ nítorí pé Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ jẹ́ òtítọ́, Ó jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tí Ó ń ṣe, àwọn ète Rẹ̀ di mímú ṣẹ, ayé sì kún fún ìfẹ́ Rẹ̀ tí kò kùnà.
Kí ni ó túmọ̀ sí?
Gbogbo ìgbà ni ìdí kan wà láti yìn Olúwa, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́ pé Ó sọ̀rọ̀, ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀ sì wà. Bákannáà, ronú pé Ẹlẹ́dàá Ọ̀run àti Ayé ti fi èrò rẹ̀ hàn sí ìṣẹ̀dá Rẹ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ - Bíbélì. Ìwé Mímọ́ ṣe àfihàn òdodo Ọlọ́run, olódodo, aláàánú, àti olóòtítọ́ láti àtètẹkọ́se. Awọn ète tí Oluwa ní fún ọjọ́ iwájú dájú bíi ìtàn àrọ́bá; kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó lè dá ètò Rẹ̀ dúró. Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run tí ó sì fi gbogbo ìrètí rẹ̀ sínú ohun tí a kọ sínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lè kún fún ayọ̀, nígbà tí ó ṣì ń dúró de ètò Rẹ̀ láti ṣẹ.
Báwo ni kí n ṣe dáhùn?
A máa ń sọ pé orin jẹ́ èdè gbogbo àgbáyé; Ó ní agbára láti ṣí àwọn ẹ̀dùn wa a sì máa gbà wá láàyè ifarahan ara ẹni. Irúfẹ́ ààyò orin yàtọ̀, síbẹ̀síbẹ̀, kódà láàárín ìjọ. A lè gbé ọkàn wa sókè lórí ẹ̀yà àwọn orin tí a yàn títí a ó fi pàdánù ìdí fún kíkọ orin ní àkọ́kọ́. Àwọn àbùdá Ọlọ́run, ìṣe, àti ète Rẹ̀ gbogbo jẹ́ ìdí tí a fi nílò láti bú jáde sí ìyìn, yálà pẹ̀lú orin inú ìwé láti àtijọ́ tàbí orin ìyìn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ. Ní ọjọ́ Àìkú yìí, fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ inú orin kọ̀ọ̀kan tí o kọ - wọ́n kún fún òtítọ́ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tí kò bá mọ́ ọ lára láti kọrin ní gbangba, gbájú mọ́ sísọ àwọn ọ̀rọ̀ náà fún Ọlọ́run pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìyìn. Báwo ni a ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́ nígbà tí a bá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí láti yìn Ín?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More