Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 102 nínú 106

Kíni ó sọ?

Nítorí pé Dáfídì rẹ̀wẹ̀sì, tí ó wà ní òun nìkan, tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì wó palẹ̀, ó gbàdúrà fún ìṣẹ́gun, ìtọ́sọ́nà, àti ọkàn tí ó ń mú inú Ọlọ́run dùn.

Kíni ó túmọ̀ sí?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la kọ àwọn sáàmù wọ̀nyí nínú ìgbésí ayé Dáfídì, ó dojú kọ ìṣòro tí ó jọ ara wọn. Nínú Sáàmù 142, Sọ́ọ̀lù ń gbìyànjú láti pa Dáfídì, nínú Sáàmù 143, Ábúsálómù ọmọ rẹ̀ ló halẹ̀ mọ́ ẹ̀mí rẹ̀. Láàárín àkókò méjèèjì, ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì, àìlera, àti àìnírètí rẹ̀ mú kí àwọn àdúrà wọ̀nyí jọra gan-an. Títí ìyàtọ̀ ńlá fi hàn ní 143:5. Ìṣòtítọ́ Ọlọ́run ní ipò àkọ́kọ́ yìí fún Dáfídì ní ìgbọ́kànlé nínú dídára Ọlọ́run àti ìfẹ́ tí kì í kùnà nínú ipò tó wà nísinsìnyí. Ìwòye Dáfídì yípadà nígbàtí ó ṣe rántí bí Ọlọ́run ṣe gbàá ṣáájú àkọ́kọ́ yí. Kò ṣe àkíyèsí ohun tí Ọlọ́run lè ṣe fún u nìkan - ó ti ní ìrírí rẹ̀ tẹ́lẹ̀

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Gbogbo ìpèníjà tí ó n kojú ń fúnni ní àyè láti ní ìmọ̀ síwájú síi nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti bí Ó ṣe ń ṣe fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀le. Ǹjẹ́ ipò tí o wà lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ ti jẹ́ kí o sú ọ tàbí ó mú ọ rẹ̀wẹ̀sì bí? Bí o bá jẹ́ onígbàgbọ́ tí ó dàgbà dénú, wo àwọn ipò mìíràn tí ó ti kọjá sẹ́yìn tí ó ti dàbí wipe kòsí írètí. Báwo ni Olúwa ṣe fún ọ ní okun láti la àwọn ìṣòro yẹn ja? Tí o bá jẹ́ Krìstìánì titun, bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run kí ó ṣí ojú rẹ kí o lè ríi bí Ó ṣe fẹ́ràn rẹ tó. Lónìí, rántí pé Ọlọ́run ṣe àmọ̀já àti yí àwọn ipò àìnírètí sí àǹfààní tó kani-láyà láti lè ṣe àfihàn oore, ọgbọ́n, àti agbára Rẹ̀

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org