Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Worship: A Study in Psalms

Ọjọ́ 105 nínú 106

Kíni ó sọ?

Onísáàmù ń yin ó sì gbẹ́kẹ̀lẹ́ Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí pé òtítọ́ Rẹ̀ dúró. Ó pe Ísírẹ́lì níjà láti yin Ọlọ́run fún àwọn òfin àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí a fihàn.

Kíni ó túmọ̀sí?

Èrò ọ̀pọ̀ ni pé wọ́n kọ sáàmù márùnún tí ó kẹ́hìn lẹ́yìn tí wọ́n ti parí tẹ́ńpìlì kejì tí wọ́n sì ti parí àtúnkọ́ ògiri Jèrúsalẹ́mù ni. Ó jẹ́ àlàyé tí ó bá a mu wẹ́kú fún ìdí tí àwọn sáàmù wọ̀nyí fi bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta pàtó yìí: “Ẹ yin Olúwa.” Nígbà ìgbèkùn Ísírẹ́lì àti ìpadàbọ̀ rẹ̀, òǹkọ̀wé náà ti kọ́ láti fi ìrètí rẹ̀ sínú Ọlọ́run dípò àwọn ènìyàn. Ẹlẹ́dàá Ọ̀run àti Ayé nìkan ni ó ń gbé àwọn tí ó ní ìdààmú ró, Ó ń gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ sókè, tí Ó sì ń wo àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn sàn. Kò ní já àwọ́n tí ó gbẹ́kẹ̀lé E kúlẹ̀. Ísírẹ̀lì ní ìdí pàtàkì láti yin Ọlọ́run; kò sí orílẹ́ èdè mìíràn tí ó ní ìfihàn ọgbọ́n Ọlọ́run àti Ẹni tí ó jẹ́ nípasẹ̀ àwọn òfin àti ìlànà Rẹ̀. Ó yẹ láti yìn Ín.

Báwo ni kí n ṣe dáhùn?

Kíni àwọn ìdojúkọ tí ò ń ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí? Tani o gbẹ́kẹ̀lé fún ìdáhùn sí wọn? Ọlọ́run ṣeé gbẹ́kẹ̀lé láti fún ọ ní ohun tí o nílò nígbà tí o bá lo àkókò nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti àdúrà. Tí o bá ń ṣe àníyàn, o lè yí padà sí I fún àlàáfíà. Tí o bá dánìkànwà, o lè yí padà sí I fún ìbádọ̀rẹ́. Tí ọkàn rẹ́ bá bàjẹ́, o lè yí padà sí I fún ìwòsàn. Tí o bá dà bí ẹni pé o kò ní agbára mọ́, o lè yí padà sí I fún agbára. O tilẹ̀ lè dúpẹ́ kí o sì yìn Ín kí àwọn ìdáhùn tó dé nítorí pé láéláé ni Ọlọ́run jẹ́ olótìtọ́ sí àwọn tí wọ́n yàn láti ní ìrètí nínú Rẹ̀.

Nípa Ìpèsè yìí

Worship: A Study in Psalms

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.

More

Ó wù wá láti dúpẹ lọ́wọ́ ilé ìjọsìn onítẹ̀bọmi L. Camden kejì tí ó wà ní òpópónà Tọ́másì Tommy fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yì i. Fún àlàyé ní kíkún sí i. jọ̀wọ́ kàn sí: http://www.trbc.org