Ìyìn: Àṣàrò nínú Orin DáfídìÀpẹrẹ

Kíni ó sọ?
Dáfídì yín Olúwa gẹ́gẹ́ bí Àpáta rẹ̀ ó sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí Ó tú àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká. Àwọn ẹnití Ọlọ́run wọn jẹ́ Olúwa jẹ́ alábùkún fún.
Kíni o túmọ̀ sí?
Dáfídì jẹ́ akíkanjú ológun ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ní ti àwọn ìdojúkọ tí ó tí ni sẹ́hìn pẹ̀lú àwọn apanirun ẹranko búburú tí wọ́n ṣe ìkọlù sì agbo ẹran bàbá rẹ̀ títí dé bí ó ṣe borí Gòláyáàtì àti gbogbo àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì, ó mọ̀ dájú pé ìṣẹ́gun wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nípa ìgbáradì, ìróni-l'agbárá, àti ìdóòlá ẹ̀mí rẹ̀. Ìjọnilójú pé Ọlọ́run Àgbáyé Ń ṣe àbójútó òun àti ìṣòro òun ṣe okùnfà bí ìjọsìn rẹ̀ ṣe gòkè àgbà síí. Dáfídì ní ìrísí àkókò kan ti àlàáfíà tí ó tinú ìbùkún, ìfẹ́, àti agbára ńlá Ọlọ́run nìkan wá
Báwo ni kí ń ṣe dáhùn?
Ǹjẹ́ o ti ní ìrírí ogun, àìlera, tàbí ikú ní ìgbésí ayé rẹ rí? Bóyá ó tí pàdánù iṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, lọ láti ibìkan sì òmíràn, tàbí ó ní ìṣòro lórí àwọn ọmọ. Dáfídì rán wa létí pé Ọlọ́run ní ìfẹ́ si ọ̀rínkiniwín ìgbésí ayé wa Óun sì dá sí wọn fún wa. Ǹjẹ́ o lè wò sẹ́yìn iye ìgbà tí Ó ti gbé ọ dìde léraléra? Báwo ní Olúwa ṣe ṣe àmúlò nkan tí ó tí kọjá sẹ́yìn ní ìgbésí ayé rẹ fún ìgbáradì rẹ láti dojúkọ àwọn ìpèníjà tí òde òní? Lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa fún bí ó ṣe rán ọ lọ́wọ́ kí ó sì béèrè fún ìtọ́sọ́nà ọjọ́ ọ̀la rẹ. Gbé ọkàn rẹ lè Ẹlẹ́dàá gbogbo Àgbáyé, ìgbé ayé rẹ yóò sì ní ipa nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, agbára àti ìfẹ́ Rẹ̀. Àwọn oríṣiríṣi wàhálà lè tún jẹ́ yọ, bákannáà ni òtítọ́ Ọlọ́run dúró láti kojú rẹ.
Key: day_103 day_103Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn sáàmù jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ewì àti àwọn orin tí a kọ ní ìkọjá ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bí àwọn Sáàmú ṣe ní àwọn ìyìn aláyọ̀ àti àwọn ìbànújẹ́ ọkàn, gbogbo ìwé náà jẹ́rìí sí ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ti Ọlọ́run ní sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ó wá ní agbedeméjì ìjọsìn Májẹ̀mú Láíláí, sáàmù kọ̀ọ̀kan ní ìrètí láti yọrí sí ìyìn Ọlọ́run nínú ikú àti àjínde Jésù Kristi.
More