Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì ÌgbàlàÀpẹrẹ

Apá kini i ìtàn ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ tààrà. Wọn jìyà, Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè tú wọn sílẹ̀, nigbana, wọn kúrò ní Egypti. Àmọ́, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni yẹn.
Ọ̀mọ̀wé Bíbélì N.T. Wright sọ ọ́ bayi,
“Ìrìn àjò òmìnira méjì ló wà nínú Ẹ́sọ́dù: mímú Ísírẹ́lì jáde kúrò nínú ẹrú ni Egypti, àti mímú ẹrú jáde kúrò nínú Ísírẹ́lì.“
Bótilẹ̀jẹ́pé wọn kò sì nínú ẹrú mọ́ nípa ti ara, Ísírẹ́lì ṣì ní àgbéronú ẹrú; wọn kò mọ láti gbé ìgbésí ayé òmìnira.
Láti mú ẹrú kúrò nínú Ísírẹ́lì, wọn ní láti mọ Ọlọ́run. Èyí sì tún mọ̀ sí mímọ orúkọ rẹ. Torí níbìkan ní ojú ọ́nà - ní àárín ìtẹ̀mọ́lẹ̀ àti ìtúsúlẹ̀ - wọn gbàgbé orúkọ Ọlọ́run. Àti nítorí náà, ẹni tí ó jẹ́ lóòtọ.
Torí ẹ, Ọlọ́run ṣe oun tí òun nikan lè ṣe: Ó fi Ara Rẹ̀ hàn.
Bí ó ṣe ń wo ìwòye bí Ọlọ́run ṣe bá Mósè pàdé nípasẹ̀ igbó to ń jó, ṣe àjíròrò lóríi agbára àti ìbásepọ̀ tímọ́ tímọ́ àsìkò yí. Fojú sí ìjìnlẹ̀ àpèjúwèé Ọlọ́run tí a fihàn nínú ìkéde alágbára yìí: “Èmi ni tí ń jẹ́ Èmi ni.” Àsìkò yìí kii se fún Mósè nìkan; ó jẹ́ fún gbogbo Ísírẹ́lì - àti àwa náà pẹ̀lú.
Ọlọ́run ò jìnà. Ó fi ara Rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi Yaweh, èyí tí ó tú mọ̀ ni Hébérù sì “Èmi ni tí ń jẹ́ Èmi ni.” Òun ni Ẹni tó wà lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ìgbà ìní wa tó jinlẹ̀ jù àti ní ìgbà iyèméjì wa tó ní agbára jùlọ.
“Báwo ni Ísírẹ́lì ṣe lè gbàgbé orúkọ Ọlọ́run?” Ṣùgbọ́n ìgbà melòó ni àwa náà ń kó sínú ìgbèkùn kan náà? Ẹ̀ melòó náà là ṣe ń fi ìgbàgbọ́ ninu Ọlọ́run sílẹ̀ nígbàtí kò bá ṣe ń kan ti a ń reti kó ṣe?
Nigbati a ba mójú kúrò lára ìrètí, a má a mójú kúrò lára ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.
Ọlọ́run kìí ṣe Elohim wa nìkan - orúkọ fún ẹni tó ní àṣẹ ni èdè Hébérù - òun ni Yaweh, orúkọ àdásọ Ọlọ́run tó fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi Olùgbèjà, Olùpèsè, Olùdáríjì, àti Olùràpadà.
Ìrìn àjò láti ìmúlẹ́rú ẹ̀ṣẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti àníyàn jẹ́ eyi tó jìn, ṣùgbọ́n Jésù wá láti rìn pẹ̀lú wa.
A lè rò pé, “Mo ti bàjẹ́,” sugbon Jésù rán wa létí pé, “Èmi ni Ẹni tó ń sọ ọ́ dọ̀tun.”
A lè ro pe, “Mo dá wà,” ṣùgbọ́n Jésù sọ pé, “Èmi ni Ẹni tí kò ní fi ọ́ sílẹ̀ láíláí.”
A lè rò pé, “Mi ò tó,” ṣùgbọ́n Jésù sọ pé, “Èmi ni.”
Ìríṣí:
Ibo láyé ẹ lọ rí ní láti jọ̀wọ́ fún Jésù láti ní ìrírí, ìsọ dọ̀tun, iwájú, àti ìpèsè rẹ̀?
Àdúrà:
Ọlọ́run, fi Ara rẹ hàn mí ní àwọn ọ̀nà tí mi ò ṣàkiyèsi rí kí n bá a lè sún mọ́ ọ dáada. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ní ìrírí bí ìtàn Ẹ́sódù ṣe lè tún ìrìnàjò rẹ ṣe lónìí. Eyi ti a mu láti inú ìwàásù Tyler Staton to pe ni “Ẹ́sọ́dù”, Ẹ̀kọ́ Bíbélì yí pè wá láti tẹ̀lé awon ọmọ Ísírẹ́lì bí wọn ṣe kúrò nínú ìmúlẹ́rú sì Ilẹ̀ Ìlérí, a sì ṣàsopọ̀ ńlá pẹ̀lú ayé Jésù àti ìṣe rẹ̀. Ṣàwárí bí ìlérí òmìnira Ọlọ́run àti àtúnṣe ṣe wà láàyè fún ọ.! Adúpẹ́ lọ́wọ́ LUMO, Tyler Station áti ìjọ Bridgetown tọ́n pèsè ètò yí. Láti wo ìwàásù Ẹ́sódù àti fún iwadi ẹ lọ sí https://bridgetown.church
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com