Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì ÌgbàlàÀpẹrẹ

Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì Ìgbàlà

Ọjọ́ 1 nínú 7

Orin kan wà tó jẹ́ wípé to ó bá tẹ́tí síi, ó rọ́hùn kárí i Bíbélì. Bọ́tilẹ̀jẹ́pé ọ̀rọ̀ wọn yàtò sí ra, adùn kan náà ni wó ní, tó sì tún ń dún lọ láyé wa lónìí.

Nínú ìtàn Ẹ́sódù, orin yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjìyà - ìnilára tó jinlẹ̀ tó jẹ́ pé ẹkùn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dìde sí ọ̀run. Ìwọ wòó: àwọn ènìyàn tó ń ké ìrora lábẹ́ àjàgà ẹrú, tí wọn ńpòǹgbẹ fún òmìnira, tí wọn ké fún ìrètí.

Ṣe ìwòye yìí ti ìnira àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Fi ara rẹ sí ipò láti lérò àìnírètí wọn àti láti gbọ́ igbe wọn bí wọn ṣe ń dúró de Ọlọ́run tó ń gbèjà wọn, tó ń pèsè fún wọn, tó ń dárí jì wọn, àti tó ń rà wọn padà.

Kíni ìdí tí ó yẹ kí á bìkítà nípa ìtàn ìtúsílẹ̀ àwọn Hébérù àtijọ́? Nítorí tí ó bá fẹ́ mọ Jésù, - ọkùnrin tí ìtàn rẹ láti kékeré wọmi pẹ̀lú ìtàn Ísírẹ́lì - Ẹ́sódù gbọdọ̀ yé ọ.

Bíi Ísírẹ́lì, ó lè ṣe ọ́ bíi ẹni tí a gbàgbé, tí àyídàyídà ń nilára, àbí to nílò ìyípadà. Ṣùgbọ́n ìtàn ìtúsílẹ̀ Ísírẹ́lì fi ǹkan tó lágbára hàn wá: Ọlọ́run ń rí, o ń gbọ́, ó sì ń súnmọ́ àwọn aláìní.

Bótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lọ yà wá, àwa àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àbápín nínú orin Ẹ́sódù: Ìṣẹ̀dá, ìmúlẹ́rú, ìtúsílẹ̀ àti àtúnṣe.

Ọlọ́run dá wa kí a lè bá òun àti oun tí ó dá gbé nínú àwùjọ ìfẹ́. Àmọ́ a já sí inú Egypti tí wa - a dì ẹrú sì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó rọrùn láti dè wá mọ́lẹ̀. Ìgbéraga wa, ojúkòkòrò, àti ifekùfẹ̀ ló fà ìní fún ìtúsílẹ̀, èyí tó jẹ́ wípé Olùgbàlà ọrùn nìkan ló lè pèsè. A nílò ìgbàlà láti ọwọ́ Egypti ti wa.

Nígbà àkókò òkùnkùn Ísírẹ́lì, Ọlọ́run fi ara rẹ hàn takun takun gẹ́gẹ́ bíi ẸNI tó ń gbéjà, tó ń pèsè, tó ń dáríjì, tó sì ń rà padà. Ó gbọ́ igbe Ísírẹ́lì, olùgbèjà wọn sì ti dé.

Ìtúsílẹ̀ wá wá láti ọ̀dọ̀ Jésù, Ọlọ́run tó ń gbani là.

Nígbà tí ìpàdánù olùfẹ́ bá fi òkùnkùn bo ayo wá, Jésù ń dúró tì wá. Nígbà tí ẹrù ojúṣe bá wúwo jù, Jésù ń dì wá mú pẹ̀lú ìtùnú ìfarahàn rẹ̀. Nígbà tí ìtìjú bá ń ru nínú wa, Jésù ń fi ojú wa si ara rẹ̀ àti òjò ọlá- tó kún fún ìrètí, ìtura àti ìdùnnú.

Ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ sí ìsin yìí, a má a ṣe àyẹ̀wò bí Jésù ṣe jẹ́ ìmúṣẹ ètò ìgbàlà tó ga jù fún aráyé. Nípasẹ̀ Rẹ̀, àti nípa òun nìkan, ni ìwọ fi lè ní ẹ́sódù tìrẹ náà.

Ìríṣí:

Kíni àwọn ẹ̀ka ìnira inú ayé rẹ tó yẹ láti mú wá sínú òmìnira Ọlọ́run?

Àdúrà:

Ọlọ́run, ó ṣé fún òmìnira tí Jésù gba fún mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti rí ọ nínú orin irin àjò ẹ́sódù mi. Àmín.

Nípa Ìpèsè yìí

Ẹ́sódù: Láti ìjìyà sì Ìgbàlà

Ní ìrírí bí ìtàn Ẹ́sódù ṣe lè tún ìrìnàjò rẹ ṣe lónìí. Eyi ti a mu láti inú ìwàásù Tyler Staton to pe ni “Ẹ́sọ́dù”, Ẹ̀kọ́ Bíbélì yí pè wá láti tẹ̀lé awon ọmọ Ísírẹ́lì bí wọn ṣe kúrò nínú ìmúlẹ́rú sì Ilẹ̀ Ìlérí, a sì ṣàsopọ̀ ńlá pẹ̀lú ayé Jésù àti ìṣe rẹ̀. Ṣàwárí bí ìlérí òmìnira Ọlọ́run àti àtúnṣe ṣe wà láàyè fún ọ.! Adúpẹ́ lọ́wọ́ LUMO, Tyler Station áti ìjọ Bridgetown tọ́n pèsè ètò yí. Láti wo ìwàásù Ẹ́sódù àti fún iwadi ẹ lọ sí https://bridgetown.church

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ OneHope fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: www.lumoproject.com